Mi ò fìgbà kan fìyà jẹ Mohbad – Sam Larry
Mary Fágbohùn
Lodi si esun ti won fi kan Sam Larry nigba ti gbajugbaja olorin Naijiria n ni, Aloba Ilerioluwa Imole ti gbogbo eniyan mo si Mohbad jade laye pe o lowosi ohun ti o yori si iku olorin naa. Sam Larry ni ohun ko mo nnkankan nipa re.
Ninu ifọrọwerọ kan laipẹ pẹlu ajafitafita Verydarkman, Sam Larry sọrọ nipa fonran to lo kaakiri to safihan pe o dojukọ Mohbad ni eti okun kan.
Fidio naa fa ibinu pẹlu bi ọpọlọpọ awọn eeyan se gbagbọ pe o jẹ ẹri ikọlu.
Sam Larry sọ pe awon eeyan fun fonran naa ni itumọ oto ni, o ṣalaye pe oun sunmọ Mohbad lati beere pe ki o da owo ere kan to gba sugbon to ko lati wa pada.
“Fidio iseju aaya ni. Mo wa pẹlu ọmọ mi ni eti okun. Nigba ti mo ri Mohbad, mo lo sọdọ rẹ ati beere pe ki o fun mi ni owo ere to gba sugbon ti ko wa. Zlatan wa nibẹ o si yara wọle lati yanju rẹ. Ko si ikọlu kankan, mi o fiya je Mohbad ni gbogbo ojo aye re, “ni o so.
Sam Larry tun soro nipa ibi to wa lakoko iku Mohbad, o ni oun wa ni Dubai, nigba ti ẹlẹgbẹ rẹ Naira Marley wa ni Amsterdam.