Mercy Chinwo kí o̩mo̩ tuntun káàbo̩
Mary Fágbohùn
Olorin ihinrere Mercy Chinwo ati oko re Olusoaguntan Blessed ni Olorun ti bukun pelu omo keji.
Ni ojo Eti, Mercy fi aworan oyun re lede lori ikanni ibanidore Facebook, lati sajoyo ire nla naa.
Tokotaya yi se igbeyawo ni ojo ketala osu kejo, 2022 ninu igbeyawo alarede ti won se ni Port Harcourt, won si bi omokunrin kan ni ojo kerin osu kokanla, 2023.
Ninu oro ifori re, o kowe pe: “Oluwa ti se e leekansii! O ti fikun ayo wa… O so erin wa di pupo…o si bukun wa pelu omo keji.”
O gbadura tokantokan, o ni “Oruko Re̩ ni a o maa gbega titi lai ninu iran wa.
Iran wa yoo ma rin ninu imole Re̩.
Nipase wa, opo yoo di alabukun,
Gbogbo orileede yoo si pe wa ni alabunkun fun.”
O tun ki oko re ku oriire, o pe ni baba meji. “Ife mi @officialblessed — baba MEJI! Oluwa dara si wa nitooto.”
Ninu idupe yii, Mercy gbe orin tuntun, Onyeoma, jade lojo Eti.
Awon ololufe ati afenifere ti fi ikinni ku oriire ranse si tokotaya ohun.
“E ku oriire, omo tuntun, kaabo si ile wara ati oyun”, enikan so bee.
Elomiran lori ikanni ibanidore Facebook wi pe: “A yin Olorun, gba ododo re, iya wa; mo sajoyo pelu re”.