Makinde sètò kọ̀m̀pútà ilèwọ́ àti ohun èlò ìkọ́ni fún olùkọ́ 18,000
Yínká Àlàbí
Onimọẹrọ Seyi Makinde tii se gomina ipinlẹ Oyo ti se eto idanilẹkọọ olukọ ẹgbẹrun mejidinlogun (18,000) jake jado ijọba ibilẹ mẹtalelọgbọn (33) to wa ni ipinlẹ naa.
Ibẹrẹ idanilẹkọọ naa ni igbakeji gomina, Barr. Abdulraheem Bayo Lawal ti pin imọ ẹrọ kọmputa ilewọ ati awon ohun elo ikọni lọlọkanojọkan fun gbogbo awọn to n se idanilẹkọọ naa.
Ileewe Emmanuel to wa ni Agbowo, Ibadan ni idanilẹkọọ naa ti waye. Barr Lawal ni eyi wa lara ipa ti ijọba ipinlẹ n ko lati le jẹ ki ipinlẹ Oyo ni eto ẹkọ to ye kooro, o ni awọn se eto yii fun awọn olukọ ki wọn le pada lọ si ileewe onikaluku wọn lati kọ awọn ọmọ ile iwe ni ẹkọ naa.
Igbakeji gomina salaye pe “ijọba se eleyii lati le jẹ ki awọn olukọ ipinlẹ b’ẹgbẹ pe nitori pe aye ti di aye kọmputa, awọn olukọ ipinlẹ Oyo naa si ni lati maa yi bi aye ba se n yi ni”.
O tun ni “kọmputa ti a n pin fun awọn olukọ yii kun fun awọn nnkan to maa mu ki idanilẹkọọ wọn rọrun pẹlu awọn nnkan ti wọn ti ko si inu rẹ”. Eyi ko tun ni jẹ ki awọn olukọ ipinlẹ Oyo ma le da kọmputa lo, wọn gbọdọ mọ ọ lo ki awọn akẹkọọ wọn to wọle idanilẹkọọ, ọsẹ meji gbako ni wọn fi maa se idanilẹkọọ naa”.
Nibe naa ni oluba-gomina-damọran lori eto ẹkọ ni ipinlẹ Oyo, Chief Suraj Abiodun Tiamy naa ti salaye pe “ọna mẹrindinlogun ni ipinlẹ Oyo ni idanilẹkọọ naa ti maa waye fun awọn olukọ yii. A si rii pe a mu ni ile iwe alakọọbẹrẹ ati girama”.
Ọkan ninu awọn olukọ to jẹ anfani naa, Arabinrin Olufisayo Fajuyigbe fi ẹmi imoore rẹ han lorukọ gbogbo awọn olukọ naa. O ni awọn mọọ loore, awọn si maa ri wi pe awọn loo bi o se yẹ ki awọn fun idagbasoke eto ẹkọ ipinlẹ Oyo.
Awọn eniyan jankan-jankan to peju pesẹ sibi iside idanilẹkọọ naa ni Alabi Baba-Asaju tii se Kọmisọna Universal Basic Education, Hon Segun Olayiwola tii se Kọmisona fun eto ẹkọ, Prof. Adelabu Solihu tii se Kọmisọna fun Establishments and Training, Alhaja Faosat Sanni tii se Kọmisọna fun Special duties ati Alhaja Wasilat Adegoke tii se kọmisọna fun Youth and Sports.
Awọn to tu ku ni Olubukola Oladipo tii se Oyo State Teaching Service Commission, Barr. Ayodele Adekanbi tii se Alaga Oyo State Agency for Persons with Disabilities, Ismael Raji tii se Alaga Nigeria Union of Teachers ati awọn miiran ti asiko ko gba wa laaye lati darukọ.