Makinde bá Chief Imam Ìbàdàn sàjo̩yò̩ o̩dún 90

Makinde bá Chief Imam Ìbàdàn sàjo̩yò̩ o̩dún 90

Yínká Àlàbí

Gomina ipinle̩ O̩yo̩, onimo̩-e̩ro̩ Seyi Makinde ni aado̩run-un o̩dun loke eepe̩ o ki n se eremo̩de. Eyi lo mu ki gomina maa ba Sheikh Abdulganiyy Agbotomokekere dupe̩ lowo̩ Allah to da e̩mi baba naa si. O ni oun mo̩ riri asiwaju rere ti Chief Imam je̩.
Imam yii ni olori awo̩n Imam ipinle̩ O̩yo̩ ati ti ile̩ Yoruba titi to fi de ipinle Edo ati Delta.
Ninu ibani-sajo̩yo̩ ti gomina fi ranse̩ lati o̩do̩ olubani-damo̩ran lori iroyin re̩, Dr Sulaimon O̩lanrewaju ni gomina salaye Imam ge̩ge̩ bi e̩ni to ni iberu O̩lo̩run to si se e fo̩kan tan.
Gomina tun fi adura sii pe ki O̩lo̩run ba wa lo̩ra e̩mi baba pelu alaafia ki awo̩n le janfani wo̩n pe̩ ni ipinle̩ O̩yo̩ ati Naijiria lapapo̩.