Makinde ṣe àtúntò ìgbìmọ̀ aláṣẹ ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́
Fẹ́mi Akínṣọlá
Gómìnà Seyi Makinde ìpíinlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti ṣe àtúntò ìgbìmà aláṣẹ ìjọba Ìpínlẹ̀ ọ̀ún.
Makinde ti yọ awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ kan nipo, o si ti rọpo wọn pẹlu awọn eeyan mii.
Gẹgẹ bi atẹjade kan ti oludamọran gomina lori eto iroyin Sulaimon Olanrewaju fi sita, Makinde ti yọ akọwe ijọba ipinlẹ Oyo, Ọjọgbọn Olanike Kudirat Adeyemo atawọn mii nipo.
Gomina si ti yan Ọjọgbọn Musibau Adetunji Babatunde gẹgẹ bi akọwe ijọba ipinlẹ Oyo tuntun.
Atẹjade ti oludamọran gomina fi sita ọhun tun fi han pe Makinde ti gbe Amofin Temilolu Seun Ashamu kuro nileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ ayika ati ohun alumọọmi ilẹ.
Ileeṣẹ ijọba to n ri si eto iṣuna ati ọrọ aje ni ni Amofin Ashamu yoo maa dari bayii.
Gomina ipinlẹ Oyo tun kede iyansipo Ọgbẹni Ademola Aderinto to jẹ ọkan lara awọn oludamọran rẹ tẹlẹ, fun ipo kọmiṣọna.
Makinde tun kede iyansipo Họnarebu Abiodun Adedoja ninu atẹjade ti oludamọran rẹ fi sita gẹgẹ bi oludamọran pataki lori idaabo bo ohun amuṣagbara.
Ọgbẹni Kolawole Elijah Akanmu ni gomina yan bayii, gẹgẹ bii oludamọran pataki lori eto iṣuna ati ọrọ aje.
Makinde yoo fi orukọ awọn eeyan to ṣẹṣẹ yan sipo yii ranṣẹ sile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo fun ayẹwo.









