Lórí owó oṣù tó kéré jùlọ Tinubu àtẹgbẹ́ òṣìṣẹ́, àáyá ń tiro, Ògúngbè ń bẹ̀rẹ̀

Lórí owó oṣù tó kéré jùlọ Tinubu àtẹgbẹ́ òṣìṣẹ́, àáyá ń tiro, Ògúngbè ń bẹ̀rè̩

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìpàdé láàárín ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ àti Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu tó wáyé ní ilé ìjọba ní ìlú Abuja ti wá sópin.

Ṣùgbọ́n wọn kò ì tíì fẹnukò lọrí owó oṣù tó kéré jùlọ fún àwọn òṣìṣẹ́.

Ààrẹ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́, Nigeria Labour Congress, Joe Ajaero àti akẹgbẹ́ rẹ̀ ti Trade Union Congress, Festos Osifo ni wọ́n ṣaájú ikọ̀ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ láti lọ ṣèpàdé pẹ̀lú ààrẹ Tinubu lórí ọ̀rọ̀ owó oṣù tó kéré jùlọ fáwọn òṣìṣẹ́ lọ́jọ́bọ̀, ọjọ́ Kọkànlá, oṣù Keje, ọdún 2024.

Níṣe ni ìrètí wà pé lẹ́yìn tí wọ́n bá parí ìpàdé náà ni ààrẹ Tinubu yóò kéde pé àwọn ti fẹnuk]o pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ àma tí èyí kò ṣẹlẹ̀.

Mínísítà fétò ìròyìn, Mohammed Idris tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìpàdé náà ṣàlàyé pé ìjíròrò ṣì ń lọ lọ́wọ́ lórí owó oṣù náà àti pé ìpàdé tí ààrẹ ṣe pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ni láti fẹnukò lórí iye kan ní pàtó.

Idris ṣàlàyé pé ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ní lẹ́yìn ìjíròrò wọn pẹ̀lú ààrẹ, ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ní kí ààrẹ fún àwọn ní ọ̀sẹ̀ láti lọ jíròrò pẹ̀lú àwọn èèyàn wọn kí wọ́n sì jábọ̀ padà nígbà náà.

Ó ní òun ní ìgbàgbọ́ pé lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan yìí, ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ àti ìjọba yóò fẹnukò lórí iye kan pàtó àti pé yóò so èso rere fáwọn ọmọ Nàìjíríà.

Ẹ ó rántí pé láti bíi oṣù mélòó kan ni ìfaǹfà ti ń wáyé láàárín ìjọba àpapọ̀ àti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ lórí owó oṣù tó kéré jùlọ.

Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ní ẹgbẹ́rùn lọ́nà igba lé ní àádọ́ta náírà (N250,000) ni àwọn ń fẹ́ gẹ́gẹ́ bí owó oṣù tó kéré jùlọ àmọ́ ìjọba àpapọ̀ àtàwọn iléeṣẹ́ aládani ní àwọn kò lè san ju ẹgbẹ́rùn méjìlélọ́gọ́ta (N62,000) lọ.

Bákan náà ni àwọn gómìnà ní àwọn kò lè san ẹgbẹ́rùn méjìlélọ́gọ́ta (N62,000) tí ìjọba àpapọ̀ ní àwọn fẹ́ san.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here