Lagelu FM, ẹbí àti ọ̀rẹ́ sèdárò Kọ́lá Ọládàpọ̀

*Ilẹ̀ ọ̀gẹ́rẹ́*

Hùn! Kín ló dé
Ilẹ̀ ọ̀gẹ́rẹ́

Kín ló ń kán ọ lójú

Kín lo fẹ́ gbà

Irú ebi kín ló ń pa ọ́

Tó ò lé mébi mọ́nú

Kín ló dé tó ò mójú nù

Kín ló dé tó ò le yááfí

Kín ló dé tó lè ṣàpamọ́ra
Kín lo fi ń sọrí

Tó o fi gbẹ̀mí ìràwọ̀ àṣẹ̀ṣẹ̀yọ

Tó o fi wólé ọlá kanlẹ̀ lógìdo

Tó o fi sọ̀kò ọ̀fọ̀ sílé aláyọ̀

Tó o fi dáṣọ ìbànújẹ́ dípò ìdùnú

Iṣẹ́ kín ló jẹ́ fún Kọ́lá

Àrọwà wo lo fi tù ú lójú

T’ọmọ Ọládàpọ̀ fi jẹ́ ọ ní hòo!

KỌ́LÁ ÒÒÒÒ!
Hàààà! KỌ́LÁ

Kín gan ló wọ̀ ọ́ lójú nílé ikú?

Ọjà wo gan ló wá títí

Tó o fi já sílé ikú dandan

Láníntán kan kìí níwo ẹṣin
Mo gbà láì janu

À mọ́ tó bá jẹ́ ti ọgbọ́n

Èdùwà fún lọ́gbọ́n

Tó bá jẹ́ ti ìmọ̀

Adániwáyé Ò gan ìmọ̀ fún ọ dénú agbárí
Bá a bá ń perí làákàyè baba ọgbọ́n

Bì ibú omi ni nínú agbárí Kọ́lá Ọládàpọ̀

Ẹ̀mì ìtẹríba níbi gbogbo

Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ dójútáyé

Ká ṣọ̀yàyà nínú ìfẹ́ dódò ikùn

Ká gbani nímọ̀ràn àtàtà ká sì tẹ́ti bẹ̀lẹ̀jẹ́

Kọ́lá Ọládàpọ̀ ò lábùyẹ

Báyé bá rí ẹni ẹni tó kú

Ẹ bí Kọ́lá ,ẹ pé irọ́ ni mo pa

Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú òtítọ́

Ó tó torí tá a bá ṣèdárò ẹni wa

Ilẹ̀ ń gbé èèyàn mi

Kọ́lá Ọládàpọ̀ ti dáṣọrọ̀gún

Olórí dúkìá mí kanlẹ̀

Kọ́lá Ọládàpọ̀ bó sọnù ẹ̀mi ò ṣe é rí he bí owó

Láwújọ akọ̀ròyìn kàròyìn
Kọ́lá ti pà ‘lẹ̀kùn ìmọ̀ dé

Kọ́lá pàlẹ̀kùn ìmọ̀ dé
pẹ̀lú àgádágodo láéláé gbére

Ìràwọ̀ tó ń tàn níṣẹ́ ìròyìn Kọ́lá darapọ̀ máwùjọ ẹbọra
A ṣìpẹ̀ ṣìpẹ̀ kíkú ó jọ̀wọ́ ẹ̀
Àlọ̀ lá rí Kọ́lá lọ kò náání àbọ̀.

Ẹni tó bá mọ ilé agbe
Kó bá ni wò ó
Ṣé ó tún ń dá aró bí ìsaájú?

Ẹni tó bá mọ ilé àlùkò kó bá ni wò ó
Ṣó sì ń ṣe osùn láì rẹ̀wẹ̀sì?

Èèyàn tó bá mọ ilé lékeǹké ó wí
Ṣé ò tẹ̀tì nínú ìkẹfun?

Eyín ká ilé
Ilé ẹ̀rín wó wómúwómú

Ẹyẹ lọ ìtẹ́ dòfò ó dòfo

Aya,ọmọ, ẹbí, ọ̀rẹ́, ìyekan

Ewúrẹ́ wọn bojú wò réré
Gbogbo wọn dúró gbári
Wọn ò réléèpo

Àgùtàn wọn bojú wò réré
Gbogbo wọn dúró gbári
Wọ́n fi eléèrí ṣàpèdáhùn

Kọ́lá Ọládàpọ̀ ò sí mọ́

Ikú ti jàwá lólè sùúná tuntun

Òkú ló jìírọ̀ orúkọ ọmọ
Kọ́lá ò dà pọ̀ mọ́ lá mọ́

Òṣùpá Kọ́lá wọ́ọ̀kùn
Bàtá Ọlá jákùn ó dìkàlẹ̀

Bá a bá tún gbìyànjú tomi lójú títí bí egbére

Ṣá a rómi ojú rojọ ṣèràpadà ẹ̀mí Kọ́lá bí

Bá a bá ràròkàn dé góǹgó ẹ̀mí
Ẹ gbọ́ ṣé ikú fojú ibẹ̀ ṣọ̀fọ̀ di ẹ̀rín

Ẹni a ròyìn ròyìn tí tí tí
nílànà àlà funfun bí aṣọ

Ẹ jẹ́ á ṣè wọ̀n láròyé
Ẹ jẹ́ á ṣè wọ̀n ní ìwíjọ́

Ẹ jẹ́ á yin Èdùwà

Ikú ló jẹ̀bi

Ìkú ti gbó tayọ ewú
Ikú ti gbó tayọ òǹkà
Ikú ti gbó tayọ ìdùnú
Ikú ń fìbànújẹ́ ṣe ayọ̀ ọ́ yọ̀ ni

Ikú lèèyàn tó dáná sunlé ìran rẹ̀ tẹ̀rín tọ̀yàyà

Ìránṣẹ́ ni gbogbo ajogun

Èdùwà Ó ṣèdájọ́ ikú

Lorí èyí Èdùwà ó gbẹ̀san ikú Kọ́lá fún wa

Ọmọ tí Kọ́lá Ọládàpọ̀ bí

kí gbogbo wọn pátá ò yàn ,kí wọn ó gbó hewú gbúrúgbúrú

Kí ẹ̀mí ìyàwó ó gùn, kí ẹbí,ọ̀rẹ́,ìyekan ó yọjú
ṣàjọyọ̀ nínú ìṣerere
Ọmọ tó fi sáyé lọ
A bèèrè ẹ̀san èyí Èdùwà

Ẹ̀bẹ̀ kan túnrè é

Má wo gbogbo ibi orí Kọ́lá Ọládàpọ̀ ti mì ní dúníyàn

gbégi lé ‘dùnú ẹ̀ ní párádísè

Àànú la bèèrè má wo àlésọ̀ wa bí ẹlẹ́ran ara.

*Fẹ́mi Akínṣọlá kí ọ pé, ó dàárọ̀ gbére, Kọ́lá Ọládàpọ̀ ,Mr Nice Guy Lagelu FM.*

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here