Labour Party,Alágá igun ẹ̀gbẹ́ di mèjì tó fẹ́̀ rojọ́ ẹ̀hónú ìbò Ààrẹ
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn àgbà bọ̀,wọ́n ní bí ọ̀rọ̀ ńlá ò bá tíì tán, èèyàn ńlá ò ní-ín sinmi.
Ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò Ààrẹ èyí tó ń lọ ní Abuja ti sún ìgbẹ́jọ́ olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party, Peter Obi èyí tó pè tako Ààrẹ tí ìlú ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn, Bola Ahmed Tinubu síwájú.
Alága àpapọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú LP, Julius Abure báwọn péjú silé ẹjọ́ tí Lamidi Apapa tí òun náà jẹ́ alága ikọ̀ kan ní ẹgbẹ́ náà sì wà ní ìkàlẹ̀.
Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni ìgbìmọ̀ ọ̀hún ti ṣáájú sún sí ọjọ́ Kẹtàdínlógún, oṣù Karùn-ún nígbà tí Peter Obi tọrọ ààyè láti sún ìgbẹ́jọ́ náà síwájú.
Nígbà tí Adájọ́ tún dé ibi ìjókòó lọ́jọ́rú láti tẹ̀síwájú ètò náà ló tún kọ̀ láti ṣe ìdámọ̀ ẹgbẹ́ Labour Party yàtọ̀ sí Obi nìkan.
Lẹ́yìn náà ni ohun tó fẹ́ jọ bí eré orí ìtàgé tún wáyé ní ilé ẹjọ́ nígbà tí wọn ò mọ ẹni tí yóò ṣojú ẹgbẹ́ nílé ẹjọ́ nínú àwọn alága méjèèjì tó wà níkàlẹ̀.
Ìgbìmọ̀ náà kọ̀ láti gbà kí Lamidi Apapa àti olórí àwọn obìnrin ẹgbẹ́, Dudu Manugu dúró gẹ́gẹ́ bí aṣojú ẹgbẹ́ nígbà tí wọ́n ní kí wọ́n yọjú.
Adájọ́ Haruna Tsamani ní tí ènìyàn méjì bá ń dúró fún ẹgbẹ́ kan ṣoṣo, àwọn kò ní gbà wọ́n wọlé.
Nígbà tí ìgbẹ́jọ́ bẹ̀rẹ̀, agbejọ́rò Labour Party, Livy Uzoukwu sọ fún ilé ẹjọ́ pé àsìkò tí wọ́n fún àwọn láti fi kó àwọn ẹ̀rí wá sílé ẹjọ́ kò tó rárá nítorí àjọ elétò ìdìbò náà kò ì tíì fún àwọn ní gbogbo nǹkan tí àwọn ń bèèrè fún.
Uzoukwu ní ìdá ọgbọ̀n nínú gbogbo àwọn ìwé tí àwọn ń bèèrè fún ni INEC ṣẹ̀ṣẹ̀ pèsè fún àwọn.
Bákan náà ló ní gbogbo àwọn ẹ̀rí tí àwọn ń bèèrè láti ìpínlẹ̀ Rivers ni wọn kò ì tíì pèsè fún àwọn bí ọ̀gá àgbà àjọ INEC ìpínlẹ̀ ṣe ní àwọn kò ní fọ́ọ̀mù EC8A, tó sì kọ̀ láti kọ ìwé láti fi èyí múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ṣe sọ fun.
Nígbà tó ń fèsì, agbẹjọ́rò INEC, Abubakar Mahmoud ní gbogbo nǹkan tí agbẹjọ́rò Labour Party ń sọ ya òun lẹ́nu gidi nítorí àwọn ni wọ́n kọ̀ láti yọjú síbi ìpàdé tí àwọn pé.
Mahmoud ní nígbà tí àwọn tún fi ìpàdé sí ọjọ́ mìíràn, wọ́n tún bínú jáde kúrò níbẹ̀.
Bákan náà ló ní gbogbo ohun èlò ìbò ti ìpínlẹ̀ Sokoto àti Rivers ló wà nílẹ̀ àmọ́ Labour Party kọ̀ láti san owó mílíọ̀nù kan àbọ̀ náírà fún ìpínlẹ̀ Sokoto àti pé fọ́ọ̀mù EC8A tí Rivers ni àwọn kò ì tíì fún wọn.
Ó fi kun pé àwọn ìwé kan náà wà tí àwọn fún ẹgbẹ́ wọn ṣùgbọ́n tí wọ́n kọ̀ láti gbà, tí wọ́n ní àfi ìgbà tó bá pé.
Ó tẹ̀síwájú pé gbogbo nǹkan tó yẹ ni àwọn ń ṣe láti ri dájú pé àwọn ran ìgbìmọ̀ náà lọ́wọ́ láti ṣe ojúṣe rẹ̀.