Láàrín ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun àti Gbenga Daniel ariwo ńlá sọ
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé àwọn àgbà sọ pé ẹni à n nà kan kìí dákẹ́ bí bẹ́ ẹ̀ kọ́ tara rẹ̀ yóó bá dákẹ́ ní ọ̀rọ̀ gómìnà tẹ́lẹ̀ tó tún jẹ sẹnetọ tó ń sojú ẹkù ìdìbò ìlà oòrùn ìpínlè ọhun rí bí Ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn ń ké sí I pé ohun tí òfin sọ nípa àwọn dúkìá rẹ tí wọ́n fẹ wó ni kó tẹ̀lé dípò kó máa wá ojú àánú kiri.
Kayode Akinmade, to jẹ agbẹnusọ gomina Dapo Abiodun lo sọ bẹẹ nigba to n sọrọ lori ile Daniel to wa ni Asọludẹrọ ati ile itura rẹ, Conference Hotel ti wọn fẹ dawo.
Ṣaaju ni gomina tẹlẹ ri naa, Gbenga Daniel, ti kọkọ ke gbajare lori awọn dukia ọhun ti ijọba to wa lode fẹ wo labẹ aṣia aato ipinlẹ naa ti wọn kọ lọdun 2022.
Daniel sọ pe gbogbo ohun to yẹ ki oun ṣe lọdọ ijọba loun ṣe ki oun to kọ awọn dukia naa ati pe ko si eyikeyi ninu rẹ ti oun kọ lai kọkọ gba aṣẹ ijọba.
O sọ siwaju si pe igbesẹ ijọba lati wo ile oun to wa ni Ṣagamu ati ile itura Conference Hotel lọwọ oṣelu ninu.
Amọ nigba to n sọrọ, Akinmade sọ pe gbogbo awọn to kọ ile si agbegbe ti Daniel kọ tirẹ si ni wọn fun ni iwe, ṣugbọn kaka ki gomina tẹlẹ ọhun mu iwe iforukọsilẹ ile rẹ lọ si ọọfisi ti wọn yoo ti ṣayẹwo rẹ, nṣe lo n ba orukọ ijọba jẹ.
O ni “ijọba ipinlẹ Ogun ko gbogun ti Gbenga Daniel rara.
“Ohun to ṣẹlẹ ni pe, ninu igbiyanju rẹ lati mu itẹsiwaju ba ipinlẹ Ogun, Gomina Dapo Abiodun ti bẹrẹ si n kọ awọn ile igbalode, bẹẹ lo n ṣatunsẹ sawọn ilu kekeke atawọn agbegbe nla.
“Agbegbe Ibara GRA lo ti bẹrẹ iṣẹ naa niluu Abeokuta, iṣẹ ọhun yoo si tun de Sagamu atawọn GRA to wa ni Ijebu-Ode.
“Iṣẹ ọhun pe fun ki a ṣe ayẹwo awọn ile to wa lawọn agbegbe yii ki a le mọ boya wọn gba asẹ ijọba, ọrọ naa kan awọn ile gbigbe, ile ẹkọ, ile iwosan atawọn ile itaja.”
Akinmade sọ siwaju si pe “inu Sagamu GRA ni ile Otunba Gbenga Daniel wa, yatọ si ile rẹ, ijọba tun fun awọn onilẹ mii lagbegbe naa ni iwe.”
Akinmade pari ọrọ rẹ pe ohun kan to ku fun Daniel lati ṣe ni lati mu iwe iforukọsilẹ ile rẹ lọ si ọọfisi ijọba to n bojuto ọrọ naa lati yanju ọrọ to n run nilẹ.
O sọ pe igbesẹ awọn ko lọwọ oṣelu ninu bo tilẹ jẹ pe Daniel gbagbọ pe wọn mọọmọ n gbogun ti oun nitori oṣelu ni.