Kùkùkẹ̀kẹ̀ ìpalẹ̀mọ́ Olúbàdàn tuntun nílẹ̀ Ìbàdàn di ìràwọ̀ ọ̀sàn
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn àgbà bọ̀, wọ́n ní ẹni nlá ní-ín ṣe ohun nlá, bẹ́ẹ̀ ní ìpalẹ̀mọ́ Ọba tuntun nílẹ̀ Ìbàdàn, Aláyélúwà Ọba Rasidi Adéwọ̀lú Àkánmú Ládọ́jà Arùsà kínní ṣé rí bí ó ṣe jẹ́ pé tilé toko, t’ìgbẹ́ tijù ọmọbíbí ìlú ló mú ìwúyè Ọba Aláyélúwà ọ̀ún bí i ìnáwó ẹlẹ́bijẹbí bí ó ti jẹ́ pé, gbogbo agboolé nílẹ̀ Ìbàdàn ní wọ́n tá àwòràn orí adé náà mọ́ tó hàn gàdàgbà, pẹ̀lú onírúurú àkọlé tó n ṣàfìhàn bí ó ṣe jẹ́, àwọn tó ta àwòràn papàá gbé àwòràn olórí ẹbí wọn àti orúkọ agboolé wọn sínú àwòràn ìgbàlódé fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ tí a mọ̀ sí bííbọọ̀dù.
Èyí kò tán síbẹ̀, akọ̀ròyìn òwúrọ̀ tó jádé láti bèèrè lọ́wọ́ àwọn èèyàn ìlú kan nìpà kábíyèsí ọ̀hún tí ó goróyè jẹ́ kó di mímọ̀ pé èèyàn tí Orí ṣà dá ni Aláyélúwà Ọba Rasidi Adéwọ̀lú Àkànmú Ládọ́jà , torí pé ọ̀pọ̀ àwọn nnkan tí kábíyèsí náà máa n ṣe ló jẹ́ ìfaradà fún ìlú, tí kìí ṣe fún ìfẹ́ tararẹ̀.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ìlànà ọba jíjẹ́ nílẹ̀ Ìbàdàn kò lẹ́ja n bákàn nínú, àjọ ni, ẹni tí àjọ Ìbàdàn bá sì kàn tì mọ àsìkò tí yóó kó, ìyẹn ni pé, bí ọba kan bá ti gbésẹ̀, ìlànà ojú òpó tí ọba tó wàjà náà bá wà ni yóó sọ,bóyá igun tiwọn tàbí ìgun mìíràn.
Ìgùn Balógun àti igun Ọ̀tún. Ojúpòó méjéèjì yíì ló jásí ojú òpó ọba jíjẹ ni ìlú Ìbàdàn.
Kò sí àní àní pé gbogbo ètò ló ti tó báyìí fún ìwúyè Ọba Rashidi Adewolu Ladoja, gẹ́gẹ́ bí Olúbàdàn ẹlẹ́ẹ̀kẹ rìn lé ló goji lọ́jọ́ Ẹti ọ̀sẹ̀ yìí tí í ṣe ọjọ́ kẹrìndín lọ́gbọ̀n oṣù Kẹsán-án.
Ọjọ Iṣẹgun ni igbimọ to n ri si eto aabo fun iwuye Ọba Ladoja fi atẹjade kan sita ninu eyi to ti kede awọn ọna kan ti yoo wa ni titi pa atawọn ọna mii tawọn onimọtọ le gba lọjọ Ẹti.
Ajọ naa ti aarẹ ẹgbẹ CCII tẹlẹ, Oloye Bayo Oyero, jẹ alaga rẹ sọ pe titi awọn ọna kan ṣe pataki tori Aarẹ Bola Tinubu n bọ wa sibi eto iwuye naa.
Isin apapọ nilana ẹsin Kristẹni (Interdenominational service) ni wọn fi ṣide ayẹyẹ igbade naa lọjọ Aje ọsẹ yii, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹsan-an.
Aafin Olubadan to wa ni Oke Aremo, niluu Ibadan eto ọhun ti waye, ẹgbẹ CCII lo ṣagbatẹru rẹ.
Ọjọ Aṣa lo waye lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹsan-an, eyi ti wọn gbe kalẹ pẹlu ajọṣepọ ileeṣẹ ijọba to n ri si Aṣa ati Irinajo afẹ nipinlẹ Oyo.
Lẹyin eyi ni wọn ṣe idanilẹkọọ lori igbade Olubadan. Agba onpitan, Ọjọgbọn Toyin Falola, lo ṣe idanilẹkọọ ọhun.
Ọjọbọ ni wọn ya sọtọ fun isin agbayanu, eyi ti yoo waye ni Civic Centre, Idi Ape, Ibadan.
Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kẹsan-an gan-an ni Olubadan tuntun yoo gba ade ni Gbọngan Mapo bi wọn ṣe la a kalẹ.
Gẹgẹ bi Kọmiṣanna eto iroyin nipinlẹ Oyo ṣe wi nipa awọn aṣoju igbimọ Olubadan to wa nibi ipade ti wọn ti la eto yii kalẹ, o ni awọn alẹnulọrọ nipinlẹ naa ni.
Lara wọn ni: Awọn aṣoju Olubadan, Aṣipa Olubadan ti wọn yan sipo, Oba Hamidu Ajibade; Oloye Nureni Adisa ati Oloye Adeola Oloko to jẹ Akọwe iroyin fun Olubadan.
Awọn mi-in ni: Kọmiṣanna Aṣa ati Irinajo afẹ, ati ti eto awọn obinrin.
Awọn alaga ijọba ibilẹ Egbeda ati Guusu-Ila-Oorun Ibadan, awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin lati Guusu-Ila-Oorun Ibadan ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Gẹgẹ bii igbimọ naa ṣe ṣalaye, lati ago meje aarọ ọjọ Ẹti lawọn ọna naa yoo ti di titi pa.
Wọnyi ni awọn ọna ti yoo wa ni titi pa tori iwuye Ọba Ladoja gẹgẹ bi Olubadan tuntun lọjọ Ẹti:
Ọna akọkọ ti yoo wa ni titi pa ni orita Beere si gbọngan Mapo ti iwuye naa yoo ti waye.
Orita Born Photo si Oja’ba naa yoo wa ni titi pa.
Ọna miran ti yoo di titi pa lọjọ Ẹti ni orita Idi-Arere si Oja’ba.
Omii tun ni orita Itamerin si gbọngan Mapo.
Ẹwẹ, igbimọ to n ri si eto aabo fun eto iwuye naa ti ṣeto fun awọn ibikan tawọn alejo yoo gbe ọkọ si ki lilọ bibọ ọkọ le rọrun.
Ibi akọkọ tawọn alejo yoo lanfaani lati gbe ọkọ wọn si lọjọ Ẹti ni aye igbọkọsi ijọba ibilẹ Ariwa Ibadan lagbegbe Agodi.
Ibomiran ti wọn ya sọtọ fawọn alejo lati gbọkọ si ni papa iṣere to wa lẹgbẹẹ agọ ọlọpaa Yemetu.
Papa iṣere Liberty Stadium lagbegbe Oke Ado ni ibomiran ti wọn ti ya sọtọ fun ibi tawọn alejo yoo ri gbe ọkọ si lọjọ Ẹti.
Igbimọ naa tun sọ pe awọn ti pese awọn ọkọ ti yoo maa gbe awọn alejo to ni iwe ti wọn fi pe wọn dani lati ibi ti wọn gbe ọkọ wọn si lọ si gbọngan Mapo ti iwuye naa yoo ti waye.
Igbimọ naa wa rọ awọn olounjẹ atawọn ontaja mii lati de si gbọngan Mapo laarin ago mẹfa aarọ ọjọ Ẹti si ago meje ku Iṣẹju mẹẹdogun ki awọn ọna to di titi pa.
Igbimọ to n ri si eto abo fun eto iwuye Ọba Ladoja gẹgẹ bi Olubadan fikun ọrọ rẹ pe awọn ọkọ to ba tẹle Aarẹ Tinubu nikan ni yoo lanfaani lati gba awọn ọna ti yoo wa ni titi pa.