Àpẹẹrẹ mẹ́jọ láti mọ̀ pe o ní àìsàn ìtọ̀ ṣúgà, ipa rẹ̀ nínú àgọ́ ara ,àti ọ̀nà láti dènà rẹ̀

Àpẹẹrẹ mẹ́jọ láti mọ̀ pe o ní àìsàn ìtọ̀ ṣúgà, ipa rẹ̀ nínú àgọ́ ara ,àti ọ̀nà láti dènà rẹ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá

Gbémi pamọ́ kí n pa ọ́, tú mi síta kí n fi ọ́ sílẹ̀ lórúkọ tí àrùn n jẹ́,ọ̀kan lára wọn ni àìsàn ìtọ̀ ṣúgà.
Àìsàn ìtọ̀ ṣúgà jẹ́ àìsàn tó máa ń ṣokùnfà ikú tó lé ní mílíọ̀nù kan ní ọdọọdún, tó sì jẹ́ pé kò sí èèyàn tí kò lè ni.

Ohun tó máa ń ṣokùnfà àìsàn yìí ni tí ṣúgà bá ti pọ̀ jù ní ara, tí ẹ̀yà tó máa ń fọ ṣúgà kúrò lára kò lè lọ gbogbo rẹ̀.

Àìsàn yìí le ṣokùnfà kí èèyàn ní àìsàn ọkàn, àìsàn rọpá rọsẹ̀, àìsàn kíndìnrín àti kí egbò má jiná tó le mú kí wọ́n gé apá tàbí ẹsẹ̀ èèyàn.

Àjọ tó ń rí sí ètò ìlera ní àgbáyé, World Health Organization, WHO sọ pé èèyàn tó tó mílíọ̀nù 422 ló ní àìsàn ìtọ̀ ṣúgà káàkiri àgbáyé – èyí tó jẹ́ àlékún ìdá mẹ́rin sí iye àwọn tó ni ní ogójì ọdún sẹ́yìn.

Ohun tó léwu níbẹ̀ jùlọ ni pé ìdajì àwọn tó ń ní àìsàn yìí ni wọn kò mọ̀ pé àwọn ni.

Àwọn àmì àpẹẹrẹ kan wà tó jẹ́ pé tí èèyàn bá ti rí lára, ohun tó tọ́ ni pé láti lọ sí ilé ìwòsàn lẹ́yẹ ò sọkà fún àyẹ̀wò.

Lára àwọn àmì àpẹẹrẹ náà ni:

Kí òùngbẹ máa gbẹ èèyàn jù: Lára àmì tí ẹni tó bá ní ìtọ̀ ṣúgà máa ń rí ni pé òùngbẹ máa ma gbẹ wọ́n ní gbogbo ìgbà kódà bí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ mu omi tán. Èyí sì máa ń wáyé bẹ́ẹ̀ nítorí pé wọ́n máa ń tọ̀ púpọ̀.
Ìtọ̀ gbogbo ìgbà: Èèyàn ma máa tọ̀ léraléra pàápàá ní alẹ́. Ní kété tí ó bá tọ̀ ni ìtọ̀ míì yóò tún máa gbọn èèyàn.
Àárẹ̀ ara: Ẹni tó bá ní àìsàn ìtọ̀ ṣúgà ma máa ri pé ó ń rẹ òun ní gbogbo ìgbà láì ṣe iṣẹ́ tàbí wàhálà kan pàtó.
Kí èèyàn máa gbẹ: Tí o bá ri pé ò ń gbẹ ju bí ó ṣe yẹ lọ láì sí pé èèyàn ní àìsàn kan tí kò jẹ́ kí èèyàn jẹun dáadáa, ọ sàn láti lọ ṣe àyẹ̀wò àìsàn ìtọ̀ ṣúgà.
Kí ebi máa pa èèyàn léraléra: lára àmì àìsàn ìtọ̀ ṣúgà ni kí ebi máa pa èèyàn ní gbogbo ìgbà. Kódà bí èèyàn bá ń jẹun léra, ebi yóò ṣì tún máa pa èèyàn.
Kí ojú máa ṣú: Tí o bá ti ń rí àyípadà nínú bí ó ṣe ń ríran, tó jẹ́ pé ó máa ń ríran dada tẹ́lẹ̀ ṣùgbọ́n tí o kò ṣàdédé ríran bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, ó sàn láti ṣe àyẹ̀wò ìtọ̀ ṣúgà.
Kí egbò má tètè jiná: Tí egbò bá ń pẹ́ ju bí ó ṣe yẹ lọ kí ó tó jiná jẹ́ àmì àpẹẹrẹ ìtọ̀ ṣúgà.
Kí ẹnu máa bó ní gbogbo ìgbà: Àìsàn ìtọ̀ ṣúgà máa ń ṣokùnfà kí èèyàn ní egbò ní ẹnu.
Èyí ni àwọn àmì àpẹẹrẹ tó ṣe gbòógì tí ẹni tó bá ní àìsàn ìtọ̀ ṣúgà le máa rí, tó sì dára kí ẹnikẹ́ni tó bá ń rí irú àwọn àmì báyìí tètè kàn sí ilé ìwòsàn fún àyẹ̀wò àti ìtọ́jú tó péye.

Ọ̀pọ̀ ẹ̀yà ara tó fi mọ́ ọkàn, kíndìnrín, ọkàn, ojú, àti ẹsẹ̀ ni àìsàn ìtọ̀ ṣúgà máa ń kóbá.

Bí àìsàn bá ṣe pọ̀ lára sí ló máa ń ṣe àkóbá fún ara sí.

Àìsàn ìtọ̀ ṣúgà kìí jẹ́ kí ara le pèsè tàbí lo insulin, ẹ̀yà ara tó máa ń jẹ́ kí ṣúgà ara di ohun àmúṣagbára.

Tí èyí bá ti rí bẹ́ẹ̀, glucose tó máa wà nínú ẹ̀jẹ̀ èèyàn máa pọ̀ si tí kò sí máa ma ṣàkóbá fáwọn ẹ̀yà ara tó ṣe kókó láti gbé ayé ìrọ̀rùn.

Wo àwọn ọ̀nà láti dènà ìtọ̀ ṣúgà
Àwọn dókítà sọ pé àìsàn ìtọ̀ ṣúgà jẹ́ ohun tó máa ń tọ ìran àtàwọn ìgbé ayé tí èèyàn bá ń gbé.

Àmọ́ ó ṣe é ṣe àmójútó pẹ̀lú ọ̀nà wọ̀nyí:

Jíjẹ àwọn oúnjẹ aṣaralóore ní gbogbo ìgbà.
Yíyàgò fún àwọn oúnjẹ inú agolo àtàwọn ọtí ẹlẹ́rìndòdò.
Jíjẹ àwọn oúnjẹ tó ní ṣúgà ní ìwọ̀nba.
Jíjẹ àwọn èso àti ẹ̀fọ́ lọ́pọ̀ ìgbà àti àwọn oúnjẹ tí wọ́n fi ẹ̀wà ṣe.
Jíjéun lásìkò tó yẹ, tó sì dára láti dá oúnjé dúró lẹ́yìn tí èèyàn bá ti yó.
Ṣíṣe eré ìdárayá náà dára láti mú àdínkù bá iye ṣúgà tó ń wà nínú ẹ̀jẹ̀ èèyàn.
Àjọ tó ń ri sí ètò ìlera ní UK, National Health Service ní ó dára láti máa ṣe eré ìdárayá fún ó kéré tán wákàtí méjì àbọ̀ láàárín ọ̀sẹ̀ kan tó fi mọ́ ìrìn.
Yíyàgò fún sìgá mímu àtàwọn ohun tó fara pẹ jẹ́ ohun tó dára láti dènà àìsàn ìtọ̀ ṣúgà.
Lára àwọn ìgbésẹ̀ láti dènà níní àìsàn ìtọ̀ ṣúgà ni èyí àti láti gba ìwòsàn lórí rẹ̀.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here