Kókó àdéhùn márùn ún tí Tinubu buwọ́lú pẹ̀lú ìjọba Brazil ,n tí yóò bí.
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní igi kan kìí dá igbó ṣe.
Ààrẹ Nàìjíríà, Bola Tinubu ti balẹ̀ sílùú Brasília, tó jẹ́ olúìlú orílẹ-èdè Brazil, níbi tó ti ṣe ìpàdé pẹ̀lú Ààrẹ Luiz Inácio Lula da Silva.
Níbi ìpàdé náà ni wọ́n ti buwọ́lù àwọn àdéhùn márùn-ún ọtọọtọ lọ́nà àti mú ìbáṣepọ̀ tó dán mọran wáyé láàrín ìjọba orílẹ-èdè méjèèjì.
Tilu-tifọn ni awọn ologun atawọn eeyan pataki lorilẹede Brazil fi lọ pade Tinubu ni papakọ ofurufu ilu Brasília.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ Aarẹ, Bayo Onanuga fi lede loju opo X rẹ lo ti kede awọn adehun naa.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, lara awọn adehun naa lo ni nnkan lati ṣe pẹlu okoowo, ibaṣepọ laarin orilẹede mejeeji, imọ sayẹnsi, irinajo ọkọ ofurufu ati eto iṣuna.
Ọọfisi Aarẹ, Palácio do Planalto to wa ni Brasília ni wọn ti buwọlu awọn adehun ọhun nibi ti Tinubu ti kede ipadabọ ileeṣẹ Petrobras, to jẹ ileeṣẹ epo ilẹ Brazil, si Naijiria.
Tinubu sọ pe ipadabọ ileeṣẹ naa si Naijiria lẹyin ọdun marun un to fopin si ajọṣepọ rẹ pẹlu ijọba ni yoo mu idagbasoke ba ọrọ aje Naijiria.
Atẹjade Onanuga ni Tinubu sọ pe “Awa ni a ni gaasi to pọ ju, mi o ri idi ti Petrobras ko ṣe ni fẹ darapọ mọ wa lati dowopọ. Inu mi dun pe Aarẹ Lula ti ṣeleri pe eyii yoo ṣeeṣe laipẹ ọjọ.”
Aarẹ Tinubu gboriyin fun ojugba rẹ, Luiz Inácio Lula da Silva fun akitiyan rẹ lati mu isọji pada ba ibaṣepọ to wa laarin orilẹede mejeji.
O tẹsiwaju pe “ọrọ ti Naijiria ni jẹ eyii ti a ko tii fi ọwọ kan rara, o si jẹ eyii ti awọn eeyan Brazil le jẹ anfani rẹ.”
Tinubu sọ pe oun ati Aarẹ Brazil ti jiroro papọ wọn si ti ri pe orilẹede mejeji ti gba awọn nnkan to ti waye sẹyin laaye lati da ibaṣepọ wọn ru, amọ opin ti de ba ipinya naa bayii.
O fi kun pe Naijiria ti ṣetan fun ibaṣepọ ti yoo mu irẹpọ waye laarin Brazil ati Naijiria nipa paṣipaarọ imọ ẹrọ, ounjẹ, imọ sayẹnsi atawọn imọ mii.
Yatọ si imọ ẹrọ, Aarẹ Tinubu tun pe fun pinpin imọ nipa oogun ilera laarin orilẹede mejeji.
Tinubu ni lootọ ni Brazil ni imọ ẹrọ to pọ ju ti Afrika lọ, amọ o gbọdọ ṣetan lati pin imọ naa pẹlu ilẹ adulawọ.
Nigba to n sọrọ, Aarẹ Brazil sọ pe asiko ti to fun ibaṣepọ ọtun laarin Naijiria ati Brazil.
Lẹyin naa lo kede pe irinajo ofurufu taara laarin orilẹede mejeeji yoo bẹrẹ laipẹ, eyii ti ileeṣẹ Air Peace yoo maa ṣe.
Adehun irinajo ọkọ ofurufu lati Naijiria taara si Brazil, eyii ti minisiti eto irinna ọkọ ofufuru, Festus Keyamo, ati ojugba rẹ ni Brazil, Silvio Costa Filhos buwọlu
Adehun eto ẹkọ laarin orilẹede mejeji ti minisita fun ọrọ ilẹ okere Bianca Ojukwu ati ojugba rẹ Mauro Vieira buwọlu
Adehun imọ sẹyẹnsi ati imọ ẹrọ ti minisiti imọ ẹrọ Geoffrey Nnaji, ati ojugba rẹ ni Brazil, Luciana Santos buwọlu
Adehun idokoowo laarin orilẹede mejeji ti gomina banki eto ọgbin Ayo Sotinrin ati ojugba rẹ Aluísio Mercadante buwọlu