Kò ṣẹlẹ̀ rí! Bàbá Ọ̀ṣun rú igbá dípò Arugbá níbi ọdún Ọ̀sun Òṣogbo

Kò ṣẹlẹ̀ rí! Bàbá Ọ̀ṣun rú igbá dípò Arugbá níbi ọdún Ọ̀sun Òṣogbo

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ohun tó ṣẹlẹ̀ níbi ayẹyẹ ọdún Ọ̀ṣun Òṣogbo ọdún 2025 yìí ṣì n ṣe ní kàyéfì, nígbà tí Bàbá Ọ̀ṣun gba igbá lórí Arugbá tó sì bá ọmọdébìnrin náà rù ú.

Ko ṣẹlẹ ri ni eyi jẹ fun ọpọ eeyan, pẹlu bo ṣe jẹ pe obinrin ti ko ba ti i mọ ọkunrin lo maa n ru igba Osun lati ayebaye.

Lọdun 2025 yii, ọmọbinrin ọmọ ọdun meje kan, Omidan Osunbunmi Ajọkẹ Olanipekun ni wọn yan bii ẹni ti yoo ru gba Osun lọ sodo.

Osunbunmi ti ru igba ti wọn ṣe lọṣọọ naa de aaye kan, ọpọ eeyan lo si ti n ṣugbaa rẹ, ti wọn n ki i pẹlu ọ̀wọ̀ ati itẹriba.

Ṣugbọn lasiko kan, Arugba ko le tẹsiwaju ninu igba riru ọhun mọ, nigba naa ni Baba Osun si gba a lori rẹ, ti ọkunrin naa ru igba Osun.
Bi eyi ṣe waye ni ọpọ eeyan ti ko ri iru ẹ ri bẹrẹ si i fi ijọloju han.

Ọpọ eeyan bẹrẹ si i ya fọto Baba Osun to di Arugba, wọn n ya ti Arugba gangan, ti wọn fi aṣọ bo loju lai ru nnkan kan mọ.

Ṣugbọn idi to fi ri bẹẹ ati pe, ṣe ọkunrin tun n ru igba ni, lo ṣaa n kọ awọn èèyàn lominu.

Ọjọgbọn Ọba Ẹsin, Ifagbenusola Olalekan Atanda, Akọda Awo Osogbo, sọrọ.

“Ohun to ṣe koko ni igba, ẹni to ru u lo tẹle e.

” Igba mi-in wa to jẹ pe ẹni ti wọn ba mu pe yoo gbe etutu, nnkan le ṣẹlẹ ti ko ni i le gbe e.

“To ba ṣẹlẹ bẹẹ, wọn a ni ko fi ọwọ ba igba naa, oun naa lo ṣi gbe e, o kan fi ọwọ ẹlomi-in gbe e ni.

”Pe Baba Osun ru igba ko ṣe nnkan kan, lara àrà ti Osun maa n da ni.

“Baba Osun to ru igba naa ko le da a sọkalẹ, Arugba naa ni yoo pada gba a lọwọ rẹ ti yoo ba a sọ ọ kalẹ.

”Ki i ṣe pe ko ṣẹlẹ ri, ẹ o fiye si i ni. Ti wọn ba fẹẹ jade laaarọ, wọn a se oro pẹlu ọba, wọn a sọ obi, wọn a ni ṣe Arugba rẹ naa lo maa ru u, a ni bẹẹ ni.

” Igba mi-in, o le ni ko kan fi ọwọ ba a ni, o le mu Baba Osun, sugbon oun naa lo gbe e nitori o fọwọ ba a.
Ni itẹsiwaju alaye rẹ, Akọda Awo Osun sọ pe oro ni ooṣa Osun, ati pe awọn ti ko ye lo ro pe awọn kan n ru igba lasan kiri.

”Bi Imọlẹ̀ ṣe ni ka ṣe e ni a ṣe ṣe e yẹn, nnkan kan ko gbun un, bẹẹ ni ko tẹ, ki i ṣe ere ori itage la n ṣe.

“Bi a ba ni Ọsun n dara, ara àrà Osun niyẹn.

“Bi Arugba ko ba ju ọmọde bẹẹ yẹn lọ, bi Osun ba mu un lati ru igba, yoo ru u ti nnkan kan o ni i ṣẹlẹ.

“To ba wu Osun, o le ni Ayaba loun fẹ ko ru igba, Ayaba o gbọdọ kọ. O le mu Baba Osun, o le ni Ataoja funra ẹ loun fẹ.

“O lasiko ti oun ati Iya Osun a jọ wa, ti ko ni i rita, to ba ti gbe igba, Osun lo gbe yẹn. Alara l’Osun.
Gẹgẹ bi Ọjọgbọn Ifagbenusola ṣe wi ninu alaye rẹ, o ni, “Lẹyin ọdun Eledumare, Osun lo kan.

“Omi ni Eledumare fi da ile aye, Iya to fi sibẹ ni Osun.

Osogbo lo jokoo si, ibi ni ibugbe ẹ, o jade sita bi eeyan fun awọn to ba mọ ọn.”

Akọda Awo Osun sọ pe ojiṣe Olodumare ni Osun, o n ba awọn gbe ọrọ de ọrọ Rẹ, o si n daa fun awọn ti awọn n bọ Osun.

O ni omi ni Olodumare fi da ile aye, eeyan ko le yè lai si omi.

O fi kun un pe awọn Ọlọṣun ti wure fun Naijriia ati Aarẹ Bola Tinubu, ki ohun gbogbo tuba, awọn ọta Naijiria ni omi maa gbe lọ.

Ọdọọdun ni ayẹyẹ bibọ Osun Osogbo maa n waye, inu osu Ogun ti i ṣe osu Kẹjọ ni wọn si maa n ṣe e, gẹgẹ bi Akọda Awo Osun ṣe ṣalaye.

Lati origun mẹrẹẹrin agbaye ni awọn eeyan ti maa n waa ṣe ayẹyẹ ọdun Osun Osogbo.

Eyi to waye lọdun yii kasẹ nilẹ lonii, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹjọ ọdun 2025.

Gẹgẹ bi akọsilẹ ati igbagbọ, ọmọbinrin ti ko ti i mọ ọkùnrin ni Arugba Osun maa n jẹ

Ọmọbinrin naa le ti idile ọba wa.

Iṣẹ rẹ ni lati ru igba ti wọn ko awọn nnkan ọlọkan-o-jọkan sinu rẹ lọ si odo Osun.

Igbagbọ awọn Ọlọ́sun ni pe Arugba lo da bii alarina laarin awọn ati orisa Odo ti i ṣe Osun.

Mimọ ni wọn mọ Arugba fun, yoo si ti fi awọn asiko kan wa ninu ẹmi to yatọ si ohun ti awon eeyan to wa ni ayika rẹ le foju ri.

Ọpọ ero lo maa n wọ tẹle Arugba Osun lẹyin nigba to ba ru igba naa, wọn yoo ba a de ibi to n gbe e lọ kẹlẹlẹ.