Kàyééfì ! Àwọn agbébọn tú olórí Ìjọba Guinea tẹ̀lẹ̀rí sílẹ̀ .

Kàyééfì ! Àwọn agbébọn tú olórí Ìjọba Guinea tẹ̀lẹ̀rí sílẹ̀ .

Fẹ́mi Akínṣọlá

Kójú má ríbi, gbogbo ara lòògùn rẹ̀ , ní báyìí, àwọn agbébọn kan ti yabo ọgbà ẹ̀wọ̀n, wọ́n sì ti tú olórí ìjọba ológun tẹ́lẹ̀ rí lórílẹ̀ èdè Guinea, Moussa Dadis Camara sílẹ̀ kúrò ní àhámọ́ tó wà.

Adájọ́ àgbà lórílẹ̀ èdè náà ló fi dí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ lọ́jọ́ Sátidé.

Òwúrọ̀ ọjọ́ Sátidé tí ìkọlù wáyé ní ọgbà ẹ̀wọ̀n tí Camara wà, tí wọ́n sì tú Ọ̀gágun àgbà náà àti èèyàn mẹ́ta mìíràn sílẹ̀ .

Camara àti àwọn mẹ́ta yòókù ló wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n lórí ẹ̀sùn pé wọ́n lọ́wọ́ nínú ikú èèyàn tótó àádọ́jọ ní iye nínú ìfẹ̀hónúhàn kan tó wáyé lọ́dún 2009.

Gbogbo ẹnu ibodè orílè-èdè Guinea ló ti wà ní títì pa báyìí nítorí àwọn afurasí náà.

Adájọ́ àgbà lórílẹ̀èdè náà, Charles Alphonso Wright ló kéde ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún lórí Rédíò lọ́jọ́ Sátidé.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here