John Utaka di Coach ní France

John Utaka di Coach ní France

Yínká Àlàbí

Orileede Faranse ti kede agbabọọlu Super Eagles Naijiria tẹlẹ, John Utaka gẹgẹ bi akọnimọọgba fun ti Montpelliers ni abala ti awọn obinrin. Utaka lo n gba ipo lọwọ Frdric Mendy to jẹ akọnimọọgba fun awọn ikọ naa tẹlẹ.
Agbabọọlu Super Eagles tẹlẹ naa yoo maa sisẹ pọ pẹlu Baptiste Merle labẹ akoso Dirẹkitọ agba, Jean-Louis Saez.
Isẹ gidi ni isẹ naa jẹ fun Utaka nitori pe oun nikan ni akọnimọọgba akọkọ ni abala awọn obinrin ni orileede France.
Lati igba ti Utaka ti siwọ bọọlu gbigba lọdun 2018 ni o ti pọkanpọ sidii akọnimọọgba. O gba iwe asẹ UEFA ni ọdun 2022. Ki o to gba isẹ ti awọn obinrin yii, oun ni akọnimọọgba awọn ọkunrin ti ko tii pe ọdun mọkandinlogun (Montpellier’s U19).
Wọn gbaa si isẹ awọn obinrin nitori bi wọn se n fidi rẹmi, koda ipo karun un ni wọn wa ni ori atẹ bọọlu nigba ti awọn obinrin PSG ati ti Lyon wa ni ipo kin-in-ni ati ipo keji.