JAMB ní ìròyìn òféegè lásán ni ìsún-sí-wájú ìdánwò tó jáde

JAMB ní ìròyìn òféegè lásán ni ìsún-sí-wájú ìdánwò tó jáde

Ajọ JAMB to n se amojuto idanwo ase-wọle si Fasiti Naijiria lo fọnrere ni ọjọ Abamẹta pe irọ lasan ni iroyin ti awọn kan gbe jade pe ajọ naa ti sun ọjọ idanwo siwaju. Wọn ni iroyin ẹlẹjẹ ti ko lẹsẹ nilẹ ni iroyin naa.
“Iroyin ofeege kan ti tẹwa lọwọ nipa isun-siwaju idanwo JAMB ọdun 2026. A fẹ ki awọn ara ilu paapaa julọ awọn akẹkọọ to fẹ se idanwo naa gba pe irọ lasan ni awọn asini lọna kan gbe jade, gbogbo eto lo ti to lati se idanwo naa gẹgẹ bi a se laa kalẹ,” ajọ naa salaye.
JAMB ni idanwo ọdun 2026 to maa bẹrẹ ni Ọjọ’bọ, ọjọ kẹrindinlogun, osu yii titi di ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹẹdọgbọn, osu yii.
Loootọ ni idanwo ranpẹ waye ni ọjọ Abamẹta, ọjọ kejidinlọgbọn, osu kẹta jake-jado orileede yii bi o tilẹ jẹ pe ipenija waye ni awọn agbegbe kan. Awọn ọmọ to le ni ẹgbẹrun lọna igba lo yẹ ki wọn se idanrawo naa nigba ti awọn ẹgbẹrun lọna aadọjọ le diẹ raaye se tiwọn.
“Awọn ibudo ogun to ni ipenija yii ni ajọ wa ti yọ kuro fun idanwo ti osu yii,” JAMB se afikun yii.
Ajọ yii gba awọn akẹkọọ niyanju lati ma se lu jibiti bi o se wu ki o kere mọ. Paapaa julọ awọn onijibiti kan to n pariwo kiri lori ayelujara pe awọn le fi kun maaki wọn ti wọn ba sanwo.
“jibiti lasan ni gbogbo rẹ, gbogbo akẹkọọ ti ọwọ ba tẹ fun iwa ọdaran yii lo maa foju wina idajọ ajọ naa” ajọ JAMB sekilọ.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here