Ìyàwó àsè̩sègbé O̩o̩ni ti mú inú bàbá o̩ko̩ rè̩ dùn bí ó se sí omi è̩ro̩ méjì sí Ilé-ifè̩
Seunfúnmi Fágbohùn
Olori Temito̩pe̩, o̩kan lara awo̩n iyawo ase̩se̩gbe Ooni, Oba Adeyeye Ogunwusi ni o mo̩ bi oun se le ri oju rere awo̩n e̩bi o̩ko̩ re̩.
Iyawo tuntun yi ni o ti wu baba o̩ko̩ re̩ ati awo̩n eniyan Ife̩ lori nipa sisi omi e̩ro̩ si ilu lailai naa.
Temitope je̩ o̩kan lara awo̩n iyawo ase̩se̩gbe meje ti Ooni ki kaabo̩ si aafin ti awo̩n eniyan se apejuwe re̩ ge̩ge̩ bi idahun si iwa idojuti, awo̩n Olori ana -paapaa julo̩ Naomey- ti o ba o̩kan o̩ba je̩.
Temitope, ti o je̩ igbakeji alapejo Hope Alive Initiative (HAI), lo ti si omi e̩ro̩ meji si agbegbe o̩ja-tuntun, odo-ogbe, ni o̩jo̩ E̩ti.
Baba Ooni ti Ile-Ife̩, O̩mo̩o̩ba Ropo Ogunwusi, kansara sii, be̩e̩ pe̩lu ni Oba naa gboriyin fun un.
Olori Ogunwusi, ti o salaye pataki omi ni awujo̩, dupe̩ lo̩wo̩ Oba Ogunwusi fun anfaani lati se idasile̩ eto ti O̩lo̩run ni fun aye re̩.
Bi o ti so̩, O̩lo̩run ti gbe ise̩ riran awo̩n ti o ku die̩ kaa to fun le lo̩wo̩, ati wi pe ise̩ re̩ ko duro lori omi sise nikan, sugbo̩n o tun niise pe̩lu awo̩n o̩mo̩ orukan.
O ni :”Mo ro wi pe o ye̩ ki a yin iwa o̩mo̩niyan ti baba wa, Ooni hu fun jije̩ ki eleyii seese, nitori pe o nife̩e̩ gbogbo awo̩n eniyan re̩ ati awo̩n Iran Yoruba”.
Olori naa ro̩ awo̩n ara o̩ja lati lo omi naa bi o ti to̩ ati bo ti ye̩, ki wo̩n o si se itoju re̩ daradara fun lilo.
Olori na fikun un pe, o n gbagbo̩ pe omi naa yoo mu iye to dara ba idokowo awo̩n o̩lo̩ja naa.
O̩tun Babalo̩ja ti Odo-Ogbe, Oloye Olaoluwa Odeyemi, e̩ni ti o so̩ro̩ lati soju awon eniyan o̩ja na dupe̩ lo̩wo̩ Ooni ati Olori re̩ fun ife̩ ti wo̩n fihan nipa sise omi e̩ro̩ naa.
Odeyemi je̩je̩ pe wo̩n yoo lo omi naa fun anfaani gbogbo ilu.
Awo̩n eniyan pataki bi baba Ooni, Omooba Ropo Ogunwusi, Elerefe ti Erefe, Oba Mayowa Fayemi, Agbolu ti Agbaje-Ife, Oba Adekunle Adewale, ni o bu iyi kun aye̩ye̩ naa.