Ìyapa wọ ìyanṣẹ́lódì ASUU

Ìyapa wọ ìyanṣẹ́lódì ASUU

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà ní àìtọ̀ sí ojú kan ni kò jẹ́ kó hó sùù.
Látàrí ìyanṣẹ́lódì tí ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ fásitì (ASUU) kéde rẹ̀, ìgbìmọ̀ àwọn olùkọ́ yunifásítì tí a mọ̀ sí Congress of University Academics (CONUA) ti ní àwọn kò bá wọn lọ́wọ́ sí ìyanṣẹ́lódì náà ní tàwọn.

Atẹjade kan ti CONUA fi sita lọjọ Aiku, ọjọ kejila oṣu Kewaa ọdun 2025 ni wọn ti ni iyanṣẹlodi ASUU naa n da ariyanjiyan silẹ lawujọ awọn oṣiṣẹ fasiti ati awọn akẹkọọ.

Lati tan imọlẹ si ohun to ruju naa ni CONUA ninu atẹjade ti Aarẹ igbimọ naa,Ọmọwe ‘Niyi Sunmonu, buwọlu, ni wọn ti ṣalaye pe:

“Awa olori Congress of University Academics (CONUA) fẹ la a ye gbogbo eeyan, pe CONUA ko kede iyanṣẹlodi kankan, bẹẹ ni a ko kopa ninu iyanṣẹlodi to n lọ lọwọ.
Ninu atẹjade CONUA, wọn ṣalaye pe ko si idi kankan fun awọn lasiko yii lati kede ai gbọraẹniye tabi gunle iyanṣẹlodi kankan.
CONUA sọ pe nigba ti igbimọ to fẹnuko lori ajọsọ lasiko ipade oṣu Kẹwaa ọdun 2009 jokoo ipade, wọn ko pe awọn si i.

“Ẹgbẹ yii fẹhonuhan nigba naa, eyi to pada fa ipade ti a sẹ pẹlu Minisita eto ẹkọ lọjọ kọkanla, oṣu Kẹsan-an ọdun 2025.
“Nibi ipade ni Minisita ti gba ọrọ wa yẹ wo, to si ni igbimọ Yayale Ahmed yoo ri i pe gbogbo ẹgbẹ yunifasiti apapọ ni yoo kan .

” O dun mọ wa pe ileeṣẹ eto ẹkọ ti ṣe eyi.

“Bi ko ba ti i kan CONUA, ti awọn ohun ti a beere fun ko si ti i mu ariyanjiyan wa lọdọ ijọba apapọ, ko si idi kankan fun CONUA lati gunle iyanṣẹlodi”

Bẹẹ ni apa kan atẹjade igbimọ naa ka.

Wọn ni ki ẹkọ nileewe giga duro digbi lai si idiwọ ni awọn duro fun, CONUA ni oun gbagbọ ninu ajọsọ alaafia pẹlu ijọba ati awọn alẹnulọrọ.

Nigba ti wọn n ṣalaye ipo wọn lori iyanṣẹlodi yii, CONUA ṣalaye pe

“A n fi eyi rọ awọn ọmọ ẹgbẹ wa lati maa ba iṣẹ lọ labala ẹkọ ati awọn to wa ni ọfiisi eto (Academic and administrative duties).

“Iduroṣinṣin yin ati otitọ inu ṣe pataki fun ẹka ẹkọ ilẹ wa lati gunke agba.

Bakan naa ni wọn rọ awọn ọga ile ẹkọ giga lati ri i pe aabo to peye wa fun awọn ọmọ ẹgbẹ CONUA lẹnu iṣẹ wọn.

Wọn ni ki awọn akẹkọọ naa ma ṣe bẹru, nitori CONUA duro lori ipinnu rẹ lati mu ẹkọ to ye kooro wa si imuṣẹ.