Ìyá mi kò lè kọrin nítorí pé ó jẹ́ ọmọbìnrin ọba – Wasiu Ayinde
Mary Fágbohùn
Akoni Fuji Wasiu Ayinde ti gbogbo eniyan mo si KWAM 1 tabi K1 De Ultimate ti fi han wi pe iya oun to ku, Halima Anifowoshe ko ipa pataki ninu ise orin.
Ogbontarigi ọmọ ọdun mejidinlaadorin naa ṣalaye pe iya oun kọ ọ ni awọn ilana orin ati ṣiṣẹ bi olupilẹṣẹ rẹ nigba aye rẹ.
Nigba ti o n soro lori eto fun iṣẹ akanṣe tuntun rẹ, Ganusi The Album Fuji Classical, K1 De Ultimate salaye pe ilowosi iya oun si aṣeyọri iṣẹ jẹ ki oun ya orin “Mama” lati inu awo-orin naa soto fun un.
Ó ní ìyá òun fẹ́ di olórin gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́bìnrin, ṣùgbọ́n wọ́n ko fi aaye gbaa bii olórin nítorí o wa lati idile ọba àti pé ó jẹ́ obìnrin.
O sọ pe, “Orin ‘Mama’ jẹ iranti iya mi ti o tun kọ mi nipa awọn ilana orin. Iya mi bi ọdọmọbinrin jẹ akọrin, o jẹ ọmọ-binrin ọba ti ko ni anfani lati ṣe afihan iwa-ara si orin nitori eni ti o jẹ; Ọmọ-binrin ọba to wa lori ite ati obinrin ti wọn fẹ ki o gbe se igbeyawo bakan naa.
“Ṣugbọn ohun gbogbo [ẹbùn iya mi] ni Ọlọrun gbe wa si odo mi. O gbe wa si odo mi ati ni ọpọlọpọ igba o ṣiṣẹ bi olupilẹṣẹ mi, ni ọpọlọpọ igba aye rẹ. O kopa tirẹ fun idagbasoke orin mi. Nitori naa, mo ro pe o jẹ ọlọla fun mi lati ranti rẹ ati ko orin ni iranti re. ”
K1 De Ultimate padanu iya rẹ, Ọmọ-binrin ọba Halima Anifowoshe, ni oṣu kin-in-ni ọdun 2025.