- O ni ilu isokan asa bii Abu Dabhi ni ilu naa
Akeem Lasisi
Bi awon eniyan kan ba maa soro lori ilu Ilorin, won kundun lati maa so pe awon kan lo ni i, awon kan ko.
Oro eyameya to da lori ija Afonja ati Alimi, eyi to yi ipa isakoso ilu naa pada, ni won saaba maa n mu ni okundundun.
Eyi lo fa a ti a ti maa n gbo ‘Ilorin Afonja’, ‘Ilorin Geri Alimi’, ‘Ilorin Onikuraani’ ati bee bee lo.
Lopo igba, bi ija, bi ote, bi ogun lo maa n se won.
Bi o tile je pe idi maa n wa fun ironu won nigba miran, iru ironu bee kii je ki a ri ewa ati pataki Ilorin.
Sugbon ogbontarigi omo Aafirika, Ojogbon Wole Soyinka, ti pe akiyesi tomode-tagba si bi ilu Ilorin se se pataki to.
O ni Ilorin je ilu isokan agbariso asa, ti o fi iwe ilu nla Abu Dabhi, to je olu ilu orile-ede United Arab Emirates.
Soyinka yombo Ilorin, to si se afiwe yii nigba ti ile iwe giga University of Ilorin gba a lalejo lojo Aje Monday, ojo kokandinlogun osu kanrun-un odun yii.
Pelu idunnu nla ni awon alase yunifasiti naa pelu awon akekoo se gba a lalejo, ti won suuru bo o, ti won si n yo mo o.
Koda oga agba ti UNILORIN, iyen Ojogbon Wahab Egbewoe, gba Soyinka lalejo ninu oofiisi re, bo tile je pe Centre for Cultural Studies and Creative Arts ti yunifasiti naa gan-an lo pe Soyinka, latari Ose Aasa (Culture Week) ti won n se.
Nigba ti Soyinka n soro, o ni Ilorin yato ni ilu, tori o ko orisiirisii eya, esin ati asa mora.
Eyi lo fa a to fi fi we Abu Dabhi, nibi ti o ti n se ise olukoni ni New York University Abu Dabhi.
Soyinka maa di eni odun mokanle laadorun (91) ni nnkan bii osu meji si asiko yii, sugbon saka ni oro si da lenu re, to si n lo to n bo bi ileke idi.
Bakan naa, Soyinka ro awon omo adulawo ki won maa so ede won si omo won, ki ede naa ma baa parun.
Ohun to tun dun opo eniyan ninu ni pe Soyinka se ileri pe oun yoo se ipa ti oun lori idagbasoke eto eko ni yunifasiti Ilorin.
Adura IROYIN OWURO ni pe ki Olorun tubo lora emi opomulero omo Yoruba yii fun wa.