Ìpínlẹ̀ Kano lékè èsì ìdánwò NECO 2025
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣe àwọn àgbà sọ pé ìrẹ́jẹ kò sí nínú fọ́tò, bí oníkálùkù bá ṣe jókòó ni yóò ṣe bá ara rẹ̀.
Ajọ National Examinations Council (NECO) ti fi abajade idanwo oniwe mẹwaa fun ti ọdun 2025 yii sita lẹyin ọjọ mẹrinlelaadọta ti wọn ṣe idanwo naa.
Alakooso idanwo NECO, Dantani Wushishi, to fidi esi idanwo naa mulẹ ni Minna, ipinlẹ Niger, ṣalaye pe akẹkọọ to le ni miliọnu kan, (1,367,210) lo ṣe idanwo oniwe mẹwaa NECO ni 2025.
Tẹ o ba gbagbe, idanwo NECO ọdun yii waye laaarin ọjọ kẹrindinlogun oṣu Kẹfa, si ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keje.
Wọn bẹrẹ si i maaki awọn esi naa lọjọ kẹrinla oṣu Kẹjọ, wọn si pari rẹ lọjọ kọkanle lógbọn oṣu Kẹjọ ọdun 2025.
Nipa onka awọn akẹkọọ ti wọn ni wọn ṣe èrú ninu idanwo naa, Wushishi ṣalaye pe:
“Onka awọn akẹkọọ to ṣe magomago ninu idanwo ọdun 2025 yii jẹ 3,878. Eyi dinku si 10,094 to waye ni 2024. ”
Gẹgẹ bi alaye ajọ NECO, ida ọgọta (60%) akẹkọọ lo yege daadaa ninu idanwo naa.
Apapọ akẹkọọ to fi orukọ silẹ lati ṣe idanwo ọhun jẹ 1,367,210, ọkunrin jẹ 685,514, awọn akẹkọọ obinrin si jẹ 681,696.
NECO kede pe awọn to pada jokoo ṣe idanwo naa jẹ 1,358,339, ọkunrin 680,292 , obinrin 678,047.
Wọn fi kun un pe awọn ti wọn gba isọri maaki ti a mọ si credit, marun-un soke ti wọn si tun yege ninu Iṣiro ati ede Gẹẹsi, jẹ 818,492. Wọn jẹ ida 60.26 % lapapọ.
Awọn ti wọn gba maaki credit yii to ju marun-un lọ, yala wọn yege Iṣiro ati ede Gẹẹsi tabi wọn ko yege, jẹ 1,144,496. Ida 84.26% ni awọn.
Akọsilẹ ajọ NECO fi han pe awọn akẹkọọ ti eya ara pe nija ,(Awọn ti wọn ni ipenija eti) to ṣe idanwo ọdun 2025 yii jẹ 1,622. Ọkunrin inu wọn jẹ 586, awọn obinrin si jẹ 355.
Ni abala awọn akẹkọọ ti wọn ni ipenija oju, ọkunrin 111 ni wọn bi NECO ṣe kede, awọn obinrin wọn si jẹ ọgorin (80)
Awọn ti wọn jẹ àfín jẹ ọkunrin mẹtadinlaadọta (47), obinrin wọn si jẹ mẹtalelaadọta (53).
Bakan naa ni awọn akanda akẹkọọ ti ohun to n ṣe wọn n ti inu ọpọlọ wa, ti wọn ko le sọrọ tabi rin daadaa (Autism), jẹ ọkunrin mejilelọgọta (62), obinrin mẹtalelọgbọn (33).
Akẹkọọ ọgọrun-un kan le mẹwaa, (110) ni wọn ni iriran wọn ko ja gaara to, nigba ti awọn akẹkọọ ti ọwọ, ẹsẹ, atẹlẹwọ, ika ọwọ ati bẹẹ bẹẹ lọ, ko pe fun (dermatoglyphia ni wọn n pe ailera naa), jẹ ọkunrin mọkandinlaadọrun-un( 89), obinrin mẹrindinlọgọrun-un( 96 )
Ajọ NECO sọ pe ileewe mejidinlogoji (38) ni awọn mu ti wọn lọwọ si magomago lasiko idanwo ọdun 2025 yii.
Wọn ni ipinlẹ mẹtala ni wọn ti ṣe èrú naa ju, awọn yoo si pe wọn lati waa wi ti ẹnu wọn ki ajọ NECO too gbe igbesẹ ijiya lorii wọn.
Ajọ naa sọ pe awọn le yọ awọn alaboojuto idanwo kan danu – mẹta lati ipinlẹ Rivers, ọkan lati Niger, mẹta lati Abuja, ọkan lati Kano, ati ẹyọkan lati ipinlẹ Osun.
NECO kede pe oun ko ti I fi esi awọn ile ẹkọ mẹjọ kan sita nijọba ibilẹ Lamorde, ipinlẹ Adamawa.
Wọn ni eyi ri bẹẹ nitori ija ẹlẹyamẹya to waye nibẹ, ti wọn ko fi le ṣe idanwo lati ọjọ keje si ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keje ọdun 2025.
Atẹjade kan loju opo NECO, kede pe bi akẹkọọ ba fẹẹ wo esi idanwo rẹ, kinni kan ti wọn n pe ni “Result checker token”, ni yoo lo.
Eyi jẹ bii kọkọrọ ti yoo ṣilẹkun oju opo ti esi idanwo naa wa.
Ẹẹmarun-un ni wọn ni akẹkọọ le lo o ko too ma ṣiṣẹ mọ.
Eyi tumọ si pe bi wọn ba fẹẹ tun esi kan naa wo ni igba kẹfa, wọn yoo nilo ‘token’ tuntun.
Bẹẹ ni ajọ naa kede.