Ìpàdé pàjáwìrì! Àwọn,gómìnà ilẹ̀ Yorùbá dúró lórí kókó mẹ́wàá

Ìpàdé pàjáwìrì! Àwọn,gómìnà ilẹ̀ Yorùbá dúró lórí kókó mẹ́wàá

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní kí ojú má ríbi, ẹsẹ̀, ni òògùnrẹ̀
‎Àwọn Gómìnà tó wà ní ẹkùn ìwọ̀-oòrùn gúúsù Nàìjíríà se ìpàdé pàjáwìrì kan nílùú Ìbàdàn lánàá.

Ipade naa to da lori eto aabo to mẹhẹ nilẹ Naijiria, ni awọn gomina mẹfẹẹfa to wa nilẹ Yoruba peju si.

Lara wọn la ti ri gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke, gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun, gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde, Gomina ipinlẹ Ekiti, Abiodun Oyebamiji ati gomina ipinlẹ Ondo, Lucky ayedatiwa.

Ipade atilẹkunmọrise naa lo waye fun ọpọ wakati nile ijọba ipinlẹ Oyo, to wa nilu Ibadan.

‎Awọn Gomina naa, ninu atẹjade ti wọn ka si awọn akọroyin leti lẹyin ipade naa, fẹnu ko lori koko adehun mẹwaa.

Awọn Gomina mẹfẹfa naa, ki ijọba apapọ pe o seun lori ìṣe takuntakun to nṣe lati tu awọn onigbagbọ, tí àwọn agbebọn fi tipatipa mu ni igbekun ni agbegbe Eruku.

Bakan naa ni wọn se kare si itusilẹ diẹ lara àwọn ọmọ ile ẹkọ awọn Catholic to wa ni Ipinlẹ Niger to ti gba ominira lọwọ awọn agbebon.

Lara awọn koko mẹwa ti wọn fẹnuko si naa ree:

‎Gomina Ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, to gba ẹnu awọn Gomina yoku sọrọ, rọ ijọba apapọ lati jẹ ki ikọ Ọlọpa Ipinlẹ fidimulẹ jake jado awon Ipinlẹ to wa ni orile-ede Naijiria.
Wọn tun n fẹ ki aarẹ Tinubu fi awọn ikọ asọgbo ransẹ láti bẹrẹ si i ṣọ awọn igbo ijọba to wa ni gbogbo ipinlẹ mẹfẹfa to wa ni agbegbe wọn.
Wọn ni eyi lo wa lati dẹkun isẹ laabi awọn agbesunmomi ati awọn agbebon to le gba inu igbo wọle si awọn ipinlẹ mẹfẹfa to wa ni ẹkun ìwọoorun guusu Naijiria.
‎Awon Gomina naa gboriyin fun Aarẹ Tinubu lori oniruuru atunṣe to ti ba ọrọ aje ati awọn eto idagbasoke ti n lọ lọwọ ni orílẹ-ede Naijiria.
‎Lati mu ki eto aabo gbopan si ni agbegbe Guusu ìwọoorun orileede yìí, awon Gomina naa kede idasile ajọ kan ti yoo maa risi didabobo gbogbo ẹya to wa ni apa Guusu ìwọoorun Naijiria.
Ajọ DAWN ni yoo ma ṣe alabojuto ajọ tuntun yii, ti gbogbo awọn oludamọran síi awọn Gomina lori eto aabo, yoo si lẹtọ síi lati lọ fun ipese aabo jake jado awon Ipinlẹ to wa ni ẹkun ìwọoorun guusu.
‎Won ṣeleri lati maa ṣe amulo ẹrọ igbalode lati gbogun ti awọn agbesumọmi ati lati maa ba ara ẹni sọrọ.
Eyini yoo mu ki oju le ka igboke-gbodo awọn ọkọ to n kọjá ni awọn oju popo jakejado awọn Ipinlẹ to wa ni agbegbe ìwọoorun guusu lorilede yii.
‎Won rọ Aare Bola Tinubu lati fi awọn ikọ to nrisi idabobo awọn igbo ọba kaakiri Naijiria ransẹ.
‎Won tun ki gbogbo ẹgbẹ tó risi didaabo awọn eeyan bii iko Amotekun, ile iṣe Ọlọpa ati ikọ NSCDC.
Wọn si rọ wọn lati mu eto aabo lokunkundun Jake jado Ipinlẹ to wa ni Guusu ìwọoorun orile-ede Naijiria.
‎Ni igbẹyin, wọn rọ awọn olugbe ẹkun Ìwọoorun guusu Naijiria, lati bara wọn gbe pẹlu alafia, ki idagbasoke le de ba ẹkun naa.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here