Ìná tún sọ ní Ibadan, ọ̀pọ̀ dúkìá tún báa lọ
Fẹ́mi Akínṣọlá
Kò dín ní ṣọ́ọ̀bù ìtajà mẹ́ta tó jóná lágbègbè Sango ní ìlú Ìbàdàn lọ́jọ́ Ẹtì.
Iroyin sọ pe ina sọ lawọn ṣọọbu naa ni idaji ni nnkan bii agogo mẹrin.
Awọn o ṣoju mi koro, sọ pe ẹrọ amuohun tutu kan to ṣana lojiji lara ina manamana ti wọn fi si lo ran mọ ara awọn ohun elo kan ti ina naa fi di nla.
Mẹta ninu awọn ṣọọbu ti wọn kọ si ẹyin ileepo kan ti wọn n pe ni Fart Oil lagbegbe naa ni ina naa jo kanlẹ raurau ki awọn oṣiṣẹ panapana to de.
Bi o tilẹ jẹ wi pe ẹmi kankan ko ba iṣẹlẹ naa rin, sibẹ dukia bii ẹrọ amuohunruru, ọti ẹlẹrindodo at’awọn dukia miran ti owo ori wọn jẹ ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu Naira lo sọnu sinu ijamba ina naa
Ọga agba ileeṣẹ panapana ni ipinlẹ Ọyọ, Yẹmi Akinyinka ṣalaye fun awọn akọroyin pe nnkan bii agogo marun un ku iṣẹju mọkandi logun ni ọga ọlọpaa kan pe awọn lori ẹrọ ibanisọrọ lati fi ọrọ naa to wọn leti.
O ni lẹsẹkẹsẹ si ni wọn gbera lọ sibẹ ti wọn si pa ina naa.
O ni igbesẹ awọn “ni ko jẹ ki ijamba ina naa ṣọṣẹ de awọn ṣọọbu yooku