Iléẹjọ́ ò gba Akpabio gẹ́gẹ́ bíi olùdíje Sẹ́nétọ̀ ní ìpínlẹ̀ Akwa Ibom
Fẹ́mi Akínṣọlá
Iléẹjọ́ tó ń gbọ́ ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn nílùú Abuja ti wọ́gilé ìdájọ́ iléẹjọ́ gíga láti yọ Godswill Akpabio gẹ́gẹ́ bíi olùdíje sípò sẹ́nétọ̀ lábẹ́ àsíà ẹgbẹ́ òṣèlú APC fún àríwá ìwọ̀ oòrùn ìpínlẹ̀ Akwa Ibom.
Ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mẹ́ta tí Adájọ́ Damlami Senchi saájú rẹ̀ lọ́jọ́ Ajé, ni Akpabio kùnà láti pèsè àwọn ẹ̀rí lásìkò tó yẹ.
Ìgbìmọ̀ ọ̀hún tẹ̀síwájú pé Akpabio, ẹni tó ra tíkẹ́ẹ̀tì láti dupò ààrẹ Orílẹ̀ yìí lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú APC kò kópa nínú ètò abẹ́nú tó wáyé ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù karùn-ún.
Tí àjọ elétò ìdìbò INEC, tó ṣe agbátẹrù ìdibo sì kéde Udom Ekpoudom gẹ́gẹ́ bíi olùdíje ẹgbẹ́ ọ̀hún.