Iléẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn fún INEC láṣẹ láti ṣàtúntò BVAS fún ìdìbò Gómìnà

Iléẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn fún INEC láṣẹ láti ṣàtúntò BVAS fún ìdìbò Gómìnà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tó ń gbọ́ àwọn awuyewuye ètò ìdìbò sípò ààrẹ ní Nàìjíríà tó wáyé lóṣù tó kọjá ti fún àjọ INEC láǹfàní láti ṣe àtúntò ohun èlò àyẹwò olùdìbò lọ́nà ìgbàlódé, BVAS tó lò fún ètò ìdìbò sípò ààrẹ.

Èyí tako ẹ̀bẹ̀ tí olùdíje fún ipò ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú LP, Peter Obi àti ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ gbé ka iwájú ilé ẹjọ́ náà pé kó ká àjọ INEC lọ́wọ́ kò pé kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ẹ̀rọ ìgbàlódé BVAS náà, àti pé ó gbọdọ̀ gba òun láàyè láti yẹ̀ ẹ́ wò.

Àwọn ìgbìmọ̀ adájọ́ mẹ́ta tó ń gbọ́ ẹjọ́ náà ṣàlàyé pé dídá INEC lọ́wọ́ kọ́ yóó pagidínà ètò ìdìbò sípò Gómìnà àtàwọn ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ tí yóò wáyé lọ́jọ́ ọ Sátidé, ọjọ́ kọkànlá oṣù kẹta.

Agbẹjọ́ró fún INEC ṣàlàyé pé kò yẹ kí Peter Obi àti ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ bẹrù ohunkohun nítorí pé gbogbo ohun tó wà lórí àwọn ẹrọ BVAS náà ni wọ́n yóò fi pamọ́ sínú agbada ayélujára ‘server’ wọn fún ẹnikẹ́ni láti wò nígbà kúùgbà.

Àwọn agbẹjọ́ró tó ṣojú fún Peter Obi àti Atiku Abubakar, ní àwọn ohun tí àwọn nílò fún ẹjọ́ àwọn ló ṣeéṣe kí wọ́n parẹ́ bí àjọ INEC bá ṣe àtúntò BVAS rẹ̀ ọhún

Ilé ẹjọ́ kòtẹ́mi lọ́rùn fún Obi àti ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ láṣẹ láti yẹ àwọn ohun èlò gbogbo tí INEC lò fún ètò ìdìbò ààrẹ tó kọjá lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà wò fún ẹjọ́ tó pè tako ìdìbò náà.

Sùgbón, àjọ elétò ìdìbò INEC dìde tako Obi àti ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ lẹ́yìn tó ní òun fẹ́ ṣe àtúntò BVAS fún àti lò lásìkò ìdìbò Gómìnà tí yóò wáyé lọ́jọ́ Sátidé.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here