Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ikú akẹ́kọ̀ọ́ OAU kan tí wọ́n bá òkú rẹ̀ nílé àkọ́kù
Fẹ́mi Akínṣọlá
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Osun ni àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ohun tó ṣe okùnfà ikú akẹ́kọ̀ọ́ onípele àkọ́kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Obafemi Awolowo University, Ile-Ife, Treasure Salako.
Ní ọjọ́rú ni ìròyìn ní wọ́n bá òkú Treasure ní ilé àkọ́kù kan ní agbègbè Lagere, Ile Ife, ìpínlẹ̀ Osun.
Bákan náà ni wọ́n ní wọ́n bá ìgò ogun apẹ̀fọn sniper ní ẹ̀gbẹ́ òkú ọmọbìnrin náà tí ọ̀pọ̀ sì ń rò wí pé bóyá ó pa ara rẹ̀ ni.
Àmọ́ agbenusọ ọlọ́pàá Osun, Yemisi Opalola nígbà tó ń bá iléeṣẹ́ PUNCH sọ̀rọ̀ lọ́jọ́bọ̀ ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ikú ọmọbìnrin náà.
Opalola ní àwọn ti gbé òkú Treasure sí ilé ìgbókùúpamọ́sí tí ilé ìwòsàn olùkọ́ni OAUTH, Ile Ife.
Ó ní nítorí àwọn nǹkan tí àwọn ènìyàn bá lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkú náà ni wọ́n fi ń rò wí pé bóyá ó pa ara rẹ̀ ni.
Ó ṣàlàyé pé àwọn máa ṣe àrídájú rẹ̀ pé wọ́n ṣe àyẹ̀wò òkú náà láti le fìdí ohun tó gba ẹ̀mí Treasure.
Ó fi kun pé gbogbo àwọn nǹkan tó bá yẹ kí àwọn ṣe ni àwọn máa gbé ìgbésẹ̀ rẹ̀ láti fi ìdí òótọ́ múlẹ̀.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, alukoro OAU, Abiodun Olanrewaju ní kìí ṣe inú ọgbà ilé ẹ̀kọ́ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí wáyé tó sì bá àwọn òbí ọmọbìnrin náà kẹ́dùn lórí àdánù ńlá náà.
Olanrewaju ní ikú Treasure kò dùn mọ́ àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ náà nínú rárá.
Bákan náà ló rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yòókù àti àwọn ọmọ Nàìjíríà lápapọ̀ láti máa ṣe àmójútó ara wọn, kí wọ́n sì máa wòye ẹni tó bá wà ní ẹ̀gbẹ́ wọn dáradára.
Ó fi kun pé nǹkan tí àwọn gbọ́ ni pé ọmọbìnrin náà ń la àwọn ìdojúkọ kan kọjá èyí tó fa ìporúru ọkàn fún un bóyá nítorí náà ló ṣe gba ẹ̀mí ara rẹ̀.
Ó ní “a bá àwọn òbí Treasure kẹ́dùn, kò yẹ kí ẹnikẹ́ni gbé irú ìgbésẹ̀ yìí bí ó ti wù kí nǹkan tí onítọ̀hún bá ń là kọjá ṣe lè lágbára tó.”