Ilé-iṣẹ́ ológun korò ojú sí bí ìyàwó ṣójà ṣe dáná sun baálé rẹ̀

Ilé-iṣẹ́ ológun korò ojú sí bí ìyàwó ṣójà ṣe dáná sun baálé rẹ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá

Iléeṣẹ́ ológun orílẹ̀èdè Nàìjíríà ti fídií ìròyìn ikú ọmọ ológun, Samson Haruna, tó jẹ́ dókítà ní ọ̀wọ́ kẹfà iléeṣẹ́ ọmọogun Nàìjíríà (6th Battalion), ẹni tí wọ́n ní ìyàwó rẹ̀ dáná sun.

Iroyin iku oloogbe naa lo bọ sori ayelujara, ti ọpọ eeyan si ti bẹrẹ si ni ma bu ẹnu atẹlu iṣẹlẹ naa.

Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ologun fi lede, Lawal Bala Muhammed buwọlu, ọmọ ologun naa padanu ẹmi rẹ lẹyin ina jo gbogbo ara rẹ lasiko ti ede ayede bẹ silẹ laaarin oun ati iyawo rẹ, Retyit Haruna

Ni ile gbe awọn tọkọtaya yii ni iṣẹlẹ ọhun ti waye ni Wellington Bassey Barracks , Ibagwa nipinlẹ Akwa Ibom.

Ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹsan an ọdun 2025 ni iṣẹlẹ naa waye

“Iwadii fihan pe iṣẹlẹ buruku yii waye lẹyin ti edeaiyede bẹ silẹ laarin tọkọtaya naa, ti inu si bi iyawo, to si ni ki oun dana sun awọn dukia to wa ni ile wọn, to si jẹ ibẹ ni ina ti mu ọkọ naa.

Oluranlọwọ oludari ẹka to n gbe iroyin sita ni ileeṣẹ ologun fikun atẹjade naa pe awọn igbiyanju lati doola ẹmi oloogbe ṣugbọn o pada jade laye.

“Dokita Haruna farapa gan an ṣugbọn a gbiyanju lati doola ni ile iwosan Battalion Medical Facility, ko to di pe a gbe lọ si ile iwosan ikẹkọsẹ ti ipinlẹ Uyo ṣugbọn o padanu ẹmi rẹ lọjọ Keje Osu Kẹwaa ọdun 2025.

Ileeṣẹ ologun ni awọn koroju pupọ si ija laarin tọkọtaya, ti wọn si tun ba awọn mọlẹbi oloogbe kẹdun .

Bakan naa ni ileeṣẹ ologun ni awọn n duro de esi iwadii eka ileeṣẹ ọlọpaa ologun, ti wọn si rọ awọn ti ọrọ kan pe ki ṣe suuru.

Ki ṣe igba akọkọ ree ti irufẹ iṣẹlẹ yii ma waye, lọdun 2022, arabinrin kan naa dana sun ọkọ rẹ niluu Osogbo.

Ifeoluwa Akanji Bamidele àti ọkọ rẹ Boluwatifẹ Bamidele ni iṣẹlẹ wọn tu gbogbo ayelujara.