Ilé ẹjọ́ yọ okùn ẹ̀wọ̀n lọ́rùn Comfort Emmanson
Yínká Àlàbí
Ile ẹjọ magisireti to fi ikalẹ si ilu ọgba ni ipinlẹ Eko ti jawe oriji fun arabinrin Comfort to wọ baluu Ibom Air ni ọjọ Aiku to wọ iya ija pẹlu awọn osisẹ baluu naa.
Onidajọ naa, Olanrewaju Salami da ẹjọ maraarun ti awọn ọlọpaa pee naa nu nigba ti minisita ọkọ ofurufu, Festus Keyamo (SAN) kede pe Ibom Air ni awọn ko sẹjọ mọ. Minisita ni “arọwa lorisiirisii lati ọdọ awọn alẹnu lọrọ nilu ati wi pe ara obinrin naa ti fara balẹ, o ti mọ ohun ti oun se laidara. Wọn ni ki wọn gba beeli rẹ ni ilaji miliọnu naira pẹlu oniduro meji pẹlu iye owo kan naa, igba ti ko ri oniduro lo sọọ di ero ọgba kirikiri ni Eko”.