Ilé ẹjọ́ sì dúró lórí òfin tó de àwọn ọlópàá nípa gíláàsì mọ́tò dúdú
Yínká Àlàbí
Ilé-ẹjọ́ Gíga Ìpínlẹ̀ Delta tí ó fi ibujokoo rẹ̀ si Orerokpe ti se idajọ pe lati ori ọga ọlọpaa patapata, Koyode Egbetokun, Kọmísọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Delta, ati gbogbo ọlọpaa Naijiria, pe ko gbọdọ si agbofinro kankan to n da ara ilu duro nitori gilaasi mọto dudu.
Ọjọ́ keji osu kin-in-ni ọdun 2026 lo yẹ ki ofin naa bẹrẹ gẹgẹ bi alaalẹ awọn ọlọpaa.
Ile ẹjọ ni awọn agbofinro gbọdọ tẹle idajọ ile ẹjọ yii titi ti ile ẹjọ miiran tun fi maa dajọ.









