Ikú màmá Wasiu ló ń tú àsírí rẹ – Sheikh Akeugbagold
Ó ti fẹsẹ̀ kọ níbìkan ni – Kunle Ologundudu
Ẹ̀wọ̀n ọdún méjì ló wà lábẹ́ òfin (Criminal code Act 495A) fún irú ẹ̀sẹ̀ Wasiu Ayinde
Yínká Àlàbí
Oju ti awọn eniyan kan fi n wo Wasiu Ayinde ni ẹni to ni igberaga, ẹni towo n gun, ẹni ti agbara n gun ati bẹẹ bẹẹ lọ. Wọn ni o ni lati kun fun adura gidi lori awuyewuye rẹ pẹlu baluu Valuejet to waye ni papako ofurufu ti Nnamdi Azikwe ni Abuja. Nigba ti o fẹ gbe igo omi rẹ wo inu baluu ti awọn eso ibẹ ni rara.
Loju ẹsẹ ni awọn alasẹ papako ofurufu ti gba iwe irinna awọn to wa baluu naa nitori ibinu mu ki wọn fo lai jẹ ki Wasiu Ayinde wọle, iyẹn gan an kọ ni wọn pe lẹsẹ, bi ko se bi wọn se fo ti o le se iku pa Wasiu Ayinde ati awọn miiran ni papakọ naa.
Bẹẹ naa si ni ofin to de Eegun naa lo de Ẹlẹha, wọn ni Wasiu Ayinde naa ko gbọdọ fo fun osu mẹfa laarin orileede tabi jade kuro lorileede.
Alẹ ọjọ keji ni gbogbo awọn to sun mọ olorin yii ti ni ki o tete bẹbẹ loju gbogbo aye to ri aisedeede rẹ. O bẹbẹ loootọ amọ ileesẹ ọlọpaa patapata ati ti ileesẹ idajọ agba ti tẹwọ gba ẹjọ naa. Awọn amofin ti wu iru ọran naa jade pe ki ọga olorin yii lọ tete bẹrẹ si ni lo gbogbo ẹsẹ to ba mọ.
Wọn ni iru ẹsẹ rẹ ni ẹni to fẹ ja baluu gba, ti o mu foonu dani ti o si pe boya lati pe awọn to fẹ gbe isẹ buruku bẹẹ fun. Wọn ni ti ko ba ni agbẹjọro to gbona janjan, ẹwọn gbere ni. Wọn ni to ba jẹ pe o kan da baluu duro lasan pẹlu ariyanjiyan ti ko si lẹbọ lẹru, ẹwọn ọdun meji ni (Criminal Code Act) (459A).
Sheikh Akewugbagold ni ko ri bẹẹ rara, “gbogbo wa la mọ K1 De Ultimate yii tẹlẹ ki o to di pe mama rẹ salaisi, ko ni ipanle to bayii, sugbọn lati igba ti ko ti si mama mọ ni gbogbo nnkan ti n yi pada fun un.”
Dr Akewugbagold se apẹẹrẹ ihuwasi Wasiu Ayinde bii mẹfa lati igba ti mama ko ti si mọ, mama yii gan an ku ko tii pe osu mefa. “lọjọ ti mama rẹ re kaa ilẹ ni o ti bẹrẹ asọjaamu GANUSI, Ko to osu kan sira wọn o tun gba ohun Aare Tinubu silẹ nigba ti o n kii ku ti mama rẹ to ku. Awọn kan lo yẹ ki wọn gbe e sugbọn o mu u jẹ. Ko pẹ sira wọn, iyawo tun ko jade ti aye tun ni boya o n lo wọn fun nnkan ni, awọn kan ni iyawo rẹ ti pe ogun, o ti pe ọgbọn ati bẹẹ bẹẹ lọ. ko to osu kan ti o tun ni oun ti di ọmọ Sẹlẹ (Celestial Church). Ko to osu kan ti o tun kọkọ nawọ lati bọ Ooni ti Ifẹ, Oba Adeyeye Ogunwusi lọwọ. Ko to osu kan to tun fun enikan nikoo lori loju gbogbo aye nigba ti inu n bii. Ko tun pe osu kan sira wọn ti o tun fi kọ lu Alhaji Kollington Ayinla nipa olori Fuji. Bẹẹ ni ko to osu kan sira wọn ti wahala Valuejet tun fi sẹlẹ, eyi tilẹ le mẹmii rẹ lọ ti aye ko si ni parẹ.
Wasiu Ayinde ni lati dẹ diẹdiẹ, mo salaye fun un lọjọ ti a pade pe alagbara o ki n sọrọ tan, alagbara ko gbọdọ binu tan, alagbara o gbọdọ jẹun tan bẹẹ si ni alagbara ko gbọdọ sun tan nitori aye le.
Kunle Ologundudu ni Wasiu Ayinde ti fẹsẹ kọ nibi kan. O ni o le jẹ “lati ibi oye ilẹ Yoruba meji to jẹ, iyẹn Mayegun ati olori omo oba Ijebu. O ni o si le jẹ lara awọn obinrin nitori pe K1 kundun obinrin pupọ, o si le jẹ nibi isẹ rẹ tabi nnkan miiran. Ọrọ rẹ ko ki n se oju lasan. Eyi si lewu pupọ nitori o fi n jẹ ki araye maa korira gbajugbaja orin Fuji ti aye n fẹ. O fẹ maa fi tirẹ tẹ irawọ awọn ọmọọlọmọ mọlẹ”.
Ologundudu lo n se giragira bii pe Aarẹ Tinubu jẹ Aarẹ ẹbi rẹ, ko ki n mọ lọpọ igba pe Aarẹ Naijiria ni. To ba bọ ninu eleyii boya o maa kọgbọn.