Ìjọba Ọ̀yọ́ àti àbá ìsúná 2026

Ìjọba Ọ̀yọ́ àti àbá ìsúná 2026

Fẹ́mi Akínṣọlá

Gómìnà Mákindé ti gbé àbá ìsúná ₦891,985,074,480.27 kalẹ̀ níwájú àwọn asòfin ìpínlẹ̀ ọ̀hún fún ìjíròrò àti fífi òǹtẹ̀ lù fún ọdún tí ọdún 2026.

Abadofin eto isuna ti Gomina pe ni “isuna fun gbigbooro eto ọrọ-aje” ni wọn ti fẹ na 502.8bn fun eto idagbasoke nigba ti ẹka eto ẹkọ yoo gba 155.2bn.

Eto ilera ni tirẹ yoo na ijọba to N70.8bn nigba ti ẹka eto ọgbin si gbe 19.9bn.

Gomina salaye wipe aba isuna yii yoo ran ipinlẹ Ọyọ lọwọ lati mu eto ọrọ aje wọn da musemuse.

O safihan awọn isẹ ribiribi ti ipinlẹ Oyo n se, bii igbesoke papakọ ofurufu Ladoke Akintọla ti Ibadan, Ọna Ibadan olobiripo Rashidi Ladoja ati awọn akanse isẹ miran ti yoo jẹ ki ipinlẹ naa dagbasoke si.

O tunbọ salaye wi pe ipinlẹ naa yo se ayẹyẹ aadọta ọdun ninu oṣu Keji ọdun 2026 ti o si ṣe afikun wi pe ayẹyẹ naa wa fun koriya awọn ọmọ ipinlẹ Ọyọ.

Nigba to n sọrọ lori ipenija aabo to n ba orilẹ-ede Naijiria finra lasiko yii, Gomina fidi ẹ mulẹ pe Ipinlẹ Ọyọ ti se agbekale eto aabo to yanranti ni gbogbo ilu kaakiri paapaa julọ

O salaye wipe awọn ara ilu mọ ohun ti o tọ ni ilana ofin, ti o si salaye wi pe awọn ti wọn n gbin ọtẹ si aarin ilu o le ri ibo yi ni ọdun 2027.

Ninu ọrọ rẹ, Olori ile-igbimọ asofin ipinlẹ Ọyọ, Adeseun Ogundoyin kan saara si gomina fun isẹ ribiribi ti o se pẹlu eto isuna ti wọn buwọlu ni ọdun 2025.

O ṣe afikun pe abadofin yii jẹ esi ijiroro ti ijọba ti se pẹlu awọn ti ọrọ kan ni ẹkun meje ti ipinlẹ Ọyọ, ti wọn si ti gbọ erongba wọn.

O tunbọ salaye wi pe ile-igbimọ asofin kẹwaa naa ko ni kẹti lati maa ṣe ojuṣe wọn, ti awọn yoo si ri wi pe awọn sisẹ pẹlu Gomina lati ri wipe gbogbo owo ti eto isuna la kalẹ lọ bo se yẹ.

Lara awọn to peju sibi ipejọ naa ni Alaafin ilu Ọyọ, Ọba Abimbọla Ọwọade, Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Rashidi Adewolu Ladọja, Olugbọn tilu Orile-Igbọn, Ọba Francis Alao, Asẹyin ti ilu Isẹyin, Asoju Soun Ilẹ Ogbomọsọ ati awọn ladelade miran.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here