Ìjọba Ogun fèsì lórí fídíò ìrẹsì “palliative” tó gba orí ayélujára

Ìjọba Ogun fèsì lórí fídíò ìrẹsì “palliative” tó gba orí ayélujára
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé wọ́n ní bí ará ilé rẹ bá lẹ́nu, ó di dandan kí ìwọ paàpá ó lẹ́ṣẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́,omi lè tẹ̀yìn wọ̀gbín lẹ́nu mọ́ olúwaarẹ̀ lọ́wọ́.
 Ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun ti ní àwọn kan ló fẹ́ máa ba àwọn lórúkọ jẹ́ lórí ọ̀rọ̀ pínpín ìrẹsì gẹ́gẹ́ bí ètò ìrànwọ́ láti mú àdínkù bá ìṣòro tí àwọn ènìyàn ń kojú lẹ́yìn tí ìjọba àpapọ̀ yọ ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù.
Ìjọba náà ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn láti yàgò fún àwọn olóṣèlú tí wọ́n ń wá gbogbo ọ̀nà láti bu ẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ tí ìjọba àpapọ̀ àtàwọn ìjọba ìpínlẹ̀ ń gbé láti mú kí ayé rọrùn fún àwọn aláìní.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí àwọn fídíò tó gba orí ayélujára níbi tí àwọn èèyàn kan ti ń fẹ̀sùn kan ìjọba pé ìrẹsì tí kò nǹkan ni wọ́n ń fún àwọn, agbẹnusọ gómìnà ìpínlẹ̀ Ogun, Lekan Adeniran ní iṣẹ́ àwọn ẹgbẹ́ alátakò ni àwọn fídíò náà.
Adeniran ní àwọn ènìyàn ń ṣe bẹ́ẹ̀ láti tàbùkù ìṣèjọba gómìnà Dapo Abiodun ni.
Ó ní ìjọba àpapọ̀ ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà pé àwọn ìrànwọ́ náà kò sí fún gbogbo ènìyàn bíkòṣe àwọn tí kò rí ọwọ́ họrí láwùjọ.
Ó tẹ̀síwájú pé èròńgbà tí kò dára tó ni àwọn ènìyàn tí wọ́n ń gbé ìròyìn náà kiri lórí ayélujára ní láti fi bu ẹnu àtẹ́ lu bí ètò náà ṣe ń lọ dáradára láti ìgbà tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ ètò pínpín oúnjẹ ọ̀hún.
Ó fi kun pé ṣáájú ni gómìnà Abiodun ti làá mọ́lẹ̀ pé ìrànwọ́ oúnjẹ náà gbọ́dọ̀ dé ọ̀dọ̀ àwọn tó ní ẹ̀tọ́ si àmọ́ àwọn kan ló ń mọ̀ọ́mọ̀ fẹ́ sọ ìjọba lẹ́nu.
Ṣaájú ni fídíò kan ti gbá orí ayélujára níbi tí ọkùnrin kan ti fẹ̀sùn kan ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun pé ìrẹsì àpò kékeré ni wọ́n fún gbogbo àwọn tí àwọn ń gbé nínú ìletò àwọn láti pín.
Ọkùnrin náà tó pe ara rẹ̀ ní alága Sokeye CDA ní àwọn kan ló wá bá òun nílé, tí wọ́n sì gbé àpò ìrẹsì kékeré kan wá fún òun.
Ó ní wọ́n sọ pé ìrẹsì náà ló wà fún gbogbo àwọn olùgbé Ẹ́sítéètì Sokeye tí òun jẹ́ alága rẹ̀.
Ó ṣàlàyé pé ojúlé 147 ló wà nínú Ẹ́sítéétì àwọn, tí ọ̀pọ̀ ilé náà sì ní ẹbí tó pọ̀ àti pé kò yé òun bí òun ṣe máa pín ìrẹsì náà fún àwọn ènìyàn náà tó máa fi kárí.
Ó ní tí ìjọba bá fẹ́ ṣe ìrànwọ́ fún àwọn ènìyàn ó yẹ kí wọ́n ṣe ní ọ̀nà tó tọ́ nítorí gbogbo nǹkan tí wọ́n gbé fún àwọn láti pín kò tó ìdá mẹ́rin odidi àpò ìrẹsì kan.
“Tí ò bá ṣeéṣe ẹ má mú ara yín ní tipá láti ṣe ìrànwọ́ fún àwọn ènìyàn nítorí a kìí ṣe elébi ní ọ̀dọ̀ wa yìí.”
“Tí ẹ bá fẹ́ ṣe ìrànwọ́ fún wa, ẹ má fi bú wa nítorí èébú ńlá ni eléyìí jẹ́ fún wá.”
Ọkùnrin náà ní òun máa dá ìrẹsì náà padà nítorí kò sí bí òun ṣe máa pin.
Nígbà tó ń fèsì sí fídíò yìí, Adeniran ní àpò ìrẹsì tí ọkùnrin náà ń fi hàn kìí ṣe fún gbogbo àwọn tí wọ́n ń gbé nínú àdúgbò rẹ̀.
Ó ní àwọn tó ń pín oúnjẹ náà kàn gbe fún-un gẹ́gẹ́ bí alága àdúgbò rẹ̀ láti gbé fún opó kan tó bá mọ̀ tó nílò rẹ̀ nínú àdúgbò náà.
Agbẹnusọ gómìnà náà ní kàkà kí alága náà gbe fún ẹni tó yẹ, ó mọ̀ọ́mọ̀ ṣe fídíò láti fi ṣe òṣèlú tí kò dára tó.
Bákan náà ló ní àwọn àpò ìrẹsì míì ni wọ́n tún pín sí inú àdúgbò Shokeye tí ọkùnrin náà ń sọ àmọ́ tí kò gba ọ̀dọ̀ rẹ̀ kọjá nítorí ìsọ̀rí ìsọ̀rí ni wọ́n pín oúnjẹ ọ̀hún.
Ó wá rọ àwọn ènìyàn pé kí wọ́n kọ etí ọ̀gbọin sí fídíò náà nítorí kìí ṣe ohun tó wáyé gangan ni ọkùnrin náà sọ nínú fídíò  ọ̀hún.