Ìjọba Nàìjíríà kéde ọjọ́ ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ fún ibúra fún Tinubu
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ìjọba orílẹ-èdè Nàìjíríà ti kéde Ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, Oṣù Karùn-ún, ọdún 2023 gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ Ìsinmi fún àwọn aráàlú láti búrawọlé fún Ààrẹ tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn, Bola Ahmed Tinubu.
Mínísítà fún ọ̀rọ̀ abẹ́lé, Ọ̀gbẹ́ni Rauf Aregbesola tó kéde ọjọ́ ìsinmi náà, ní ọjọ́ náà wà fún ayẹyẹ ọjọ́ òmìnira Nàìjíríà.
Ṣaájú ni ọjọ́ náà jẹ́ ọjọ́ ìsinmi kí Ààrẹ Buhari tó sún Àyájọ́ Ọjọ́ òmìnira Nàìjíríà sí Ọjọ́ Kejìlá, Oṣù Kẹfà, ọdọọdún.
Àmọ́ kò ì tíì dájú bọ́yá àwọn aráàlú yóò tún gba ọjọ́ ìsinmi míràn ní ọjọ́ June 12.
Nígbà tí Ààrẹ Buhari sún ọjọ́ náà ní ọdún 2018 ní òun gbé ìgbésẹ̀ náà láti bu ọlá fún Moshood Abiola tó jáwé olúborí nínú ìdìbò ọdún June 12, 1993 àmọ́ tí ìjọba ológun dojú rẹ̀ bolẹ̀ nígbà náà.
Àwọn ẹṣọ́ aláàbò ní ohun gbogbo ló ti wà ní ṣẹpẹ́ fún ètò ìbúrawọlé tí yóó wáyé ní ìlú Àbújá.
Tinubu ni yóó jẹ́ Aàrẹ kẹrìndínlógún tí wọ́n yóó dìbò yàn gẹ́gẹ́ bí Aàrẹ ní ìjọba alágbádá ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.