Ìjọba Nàìjíríà fún àwọn àjèjì ní gbèdéke ọgbọ̀njọ́ àtúnṣe físà
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣe wọ́n ní bí a se é ṣe níbí, èèwọ̀ ibòmíràn ni.
Bí àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣe jẹ́ àjòjì ní àwọn ilẹ̀ ibò míràn tí wọ́n jápa lọ, bẹẹ ni àwọn àjèjì tó ti orílẹ-èdè míràn wá sí Nàìjíríà náà wà níbí pẹ̀lú.
Lábẹ́ òfin, ẹtọ ni fún àwọn àjèjì tó ń gbé Nàìjíríà láti ní ìwé ìwọlé jáde tí a mọ̀ sí físà, ṣùgbọ́n àwọn mìíràn kò ní.
Ọtọ ni awọn ti wọn ni iwe naa ṣugbọn ti ọjọ ti lọ lorii rẹ, ti wọn ko si sọ ọ di tuntun bo ṣe yẹ.
Nitori iru awọn eeyan mejeeji yii ni ijọba Naijiria ṣe kede ṣaaju, pe ki wọn ṣe atunṣe to yẹ ko too di oṣu Karun-un ọdun yii.
Lẹyin oṣu mẹrin ti wọn ti kede eyi ni wọn tun ṣẹṣẹ kede gbedeke tuntun bayii.
Gẹgẹ bi ileeṣẹ Nigeria Immigration Service, (NIS) to n ri si iwọle-jade lorilẹede yii ṣe kede bayii, anfaani tun ti wa fun awọn ajeji lati ṣe atunṣe iwe wọn titi di ọgbọnjọ oṣu Kẹsan-an ọdun 2025.
Ki ni yoo ṣẹlẹ lẹyin eyi? Minisita Eto abẹle, Olubunmi Tunji-Ojo, ṣalaye pe ijọba yoo bẹrẹ si fi ọwọ ofin mu ajeji ti iwe rẹ ko ba kunju oṣuwọn, bẹrẹ lati ọjọ akọkọ ninu oṣu Kẹwaa ọdun 2025.
Gẹgẹ bi ikede naa ṣe wi, anfaani gbedeke ọgbọnjọ oṣu Kẹsan-an yoo wa fun:
Awọn ti iwe wọn ti lejọ, tabi to tako ohun to wa lori iwe naa lọna kan tabi omiran.
Awọn ti iwe ti wọn ni anfaani lati lo lẹẹkan ṣoṣo tabi ju bẹẹ lọ ti kọja iye igba to yẹ ki wọn lo o.
Awọn to waa ṣiṣẹ ti wọn si ni anfaani lati gbe ilẹ yii, ṣugbọn ti ọjọ ti lọ lorii iwe wọn ju ọgbọn ọjọ lọ.
Bo tilẹ jẹ pe awọn iwe iwọle-jade kan ko ri jẹ ninu anfaani gbedeke oṣu kan yii, ileeṣẹ NIS sọ pe kawọn ẹni tiru ẹ ba kan naa ri i pe wọn ṣe isọdọtun iwe wọn tọjọ ba ti lọ lorii rẹ, ko ma baa di pe awọn n fi ọwọ ofin mu wọn.
Awọn ajeji tọrọ yii kan yoo ni lati lọ si oju opo NIS ko too di ọgbọnjọ oṣu yii, bi wọn ko ba tete ṣe bẹẹ, wọn yoo koju ofin.
Wọn yoo ni lati fi orukọ silẹ lati oju opo email wọn, nibi ti wọn yoo ṣalaye nipa ara wọn si, ti wọn yoo sọ nipa iwe irinna wọn ati idi ti wọn fi fẹẹ jẹ anfaani gbedeke yii.
Lẹyin eyi ni wọn yoo ṣafihan awọn iwe idanimọ wọn, titi kan ẹda fisa to ti lejọ naa.
Bakan naa ni wọn yoo sọ boya wọn ṣi fẹẹ maa gbe ni Naijiria lọna to ba ofin mu, tabi wọn fẹẹ kuro nilẹ yii funra wọn.
Bi wọn ba fi esi wọn naa ranṣẹ tan, wọn yoo ri idahun pe esi naa ti de ibi to yẹ ko balẹ si.
Ajeji naa yoo si le maa ri ibi to de duro nigbakugba to ba kan si oju opo naa lati mọ bo ṣe n lọ.
Ṣugbọn a ko mọ bi eto yii ṣe maa n pẹ to ko too pari.
Alaye ijọba Naijiria nipa gbedeke ti wọn fi ọjọ kun naa ni pe yoo jẹ ko han kedere pe ẹka irinna orilẹede yii ṣee fi ọkan tan.
Wọn ni yoo jẹ ko han pe akoyawọ wa, o si ṣee gbagbọ.
Yoo tun ran ijọba lọwọ lati ni akọsilẹ gidi nipa awọn ajeji to n gbe nilẹ yii, eyi yoo wulo lẹka aabo.
Lẹyin gbedeke yii, awọn ti iwe wọn ko ba tun kaju ẹ le di ẹni ti wọn n le jade ni Naijiria, nigbakigba ti ọwọ awọn agbofinro ba tẹ wọn.
Wọn si le fi ofin de wọn lati ma wọ Naijiria mọ laye.
Awọn ileeṣẹ ti awọn ajeji to n ṣiṣẹ pẹlu wọn ko ni iwe igbeluu pipe le ni lati san owo itanran, wọn si le le oṣiṣẹ naa pada si ilu rẹ, tabi ki ọrọ naa da iṣẹ paapaa duro nileeṣẹ bẹẹ.
Eyi kọ ni igba akọkọ ti ijọba Naijiria yoo fi anfaani gbedeke tuntun fun awọn ajeji to gba ọna eru wọ ilu yii, ti wọn ni ki wọn lọọ ṣe atunṣe iwe wọn bo ṣe yẹ.
Ni oṣu Keje ọdun 2019, nigba ijọba Oloogbe Muhammadu Buhari, o kede isunsiwaju oṣu mẹfa fun awọn ajeji to feru wọle si Naijiria lati lọọ tun iwe wọn ṣe.
Koda, ko nawo wọn lowo nigba naa, bẹẹ ni ko si itanran kankan fun wọn.