Ìjọba Nàìjíría fẹ fún àádọ́ta mílíọ̀nù akẹ́kọ̀ọ́ lóúnjẹ ọ̀fẹ́
Fẹ́mi Akínṣọlá
Kí la ó jẹ làgbà kí la ó ṣe, okun inú la ṣì fi ń gbé tòde.
Eyi lo mu ijọba apapọ Naijiria gun le eto fifun awọn akẹkọọ ileewe alakọọbẹrẹ ti wọn to aadọta miliọnu (50m) lounjẹ ọfẹ, bẹrẹ lati ọdun 2026 lọ.
Alabojuto eto ounjẹ ọfẹ yii, Aderemi Adebowale, ṣalaye fun ajọ Akoroyinjọ Naijiria (NAN), niluu Abuja pe, gbogbo ọna ni ijọba n gba lati mu eto ti wọn pe ni ‘National Home-Grown School Feeding” naa kẹsẹ jari.
“Afojusun wa ni lati jẹ ki awọn akẹkọọ lati iwe kin-in-ni de ikẹta, ikẹta de ikẹfa, jẹ anfaani yii, ati awọn ti ko si nileewe pẹlu, a n gbiyanju lati mu wọn wọnu eto naa.
“Nigba ti yoo ba fi di 2026, a ni ireti lati maa fun akẹkọọ alakọọbẹrẹ aadọta miliọnu lounjẹ ni Naijiria.
Nipa iye ti ounjẹ akẹkọọ kọọkan yoo jẹ, Aṣoju ijọba lori eto yii sọ pe,
” Bi ba wo o daadaa, ounjẹ ọmọ kan nileewe yẹ ko wa laaarin 500 si 1,000. Iyẹn ẹẹdẹgbẹta naira si ẹgbẹrun kan.
“Koda gan-an, pẹlu N500 fun ọmọ kan yii, o yẹ ka ṣi le fun awọn ọmọ naa ni ounjẹ aṣaraloore to dara lojumọ.”
Adebowale lo sọ bẹẹ.
O ni ki i ṣe pe ijọba yoo lọọ maa ra ibẹmbẹ ounjẹ lọja, bi ko ṣe pe awọn ti n ba awọn agbẹ kereje sọrọ, ti wọn yoo le maa gbe nnkan oko wa fun eto ounjẹ ọfẹ yii lai si iyọnu.
“Pẹlu eto yii, a maa nikapa lori iye ti a fẹẹ ra a, a o ni i ṣamulo iye ti wọn n ta a lọja.
“Lọgan ti a ba ti ni asọye pẹlu awọn ti a jọ n da owo pọ, yoo rọrun lati le fẹnuko lori iye ti ounjẹ abọ kan yoo jẹ fun ọmọ kan.”
Tẹ o ba gbagbe,ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Karun-un ọdun 2025 yii ni ijọba fi eto yii lelẹ pada, ti wọn ni awọn yoo bọ ogun miliọnu akẹkọọ atawọn ti ko si nileewe nigba naa, ki wọn too sọ ọ di aadọta miliọnu bayii.
Eto yii jẹ ọkan lara ileri ọtun (Renewed Hope) ti Aarẹ Tinubu fi polongo ibo ni 2023.
Nigba ti iṣakoso aarẹ Naijria tẹlẹ, Oloogbe Muhammadu Buhari, gbe eto yii kalẹ ni 2016, wọn pe e ni ‘National Home-Grown School Feeding Programme’ (NHGSFP). Awọn anfaani ti wọn ni yoo mu wa ni:
*Irọrun yoo ba obi ati alagbatọ nipasẹ ounjẹ.
Ipese iṣẹ fun ọpọ eeyan ni gbogbo ipinlẹ to ba ti n waye.
Ounjẹ aṣaraloore ti akẹkọọ yoo maa jẹ yoo ran ilera ati ọpọlọ wọn lọwọ.
Yoo jẹ ko maa wu awọn akẹkọọ lati maa wa sileewe deede, awọn ti wọn n kọ ẹkọ aabọ tẹlẹ yoo si dinku.
Yoo ran ipese ounjẹ labẹle lọwọ, yoo si jẹ ki ọja ta daadaa fun awọn oniṣowo.
Lẹyin ti wọn ṣe abala akọkọ eto ifunilounjẹ ọfẹ naa, nigba ti yoo fi di oṣu Karun-un ọdun 2029, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo to jẹ igbakeji aarẹ nigba naa, kede pe o ti le ni akẹkọọ 9.3 million to ti n jẹ anfaani naa ni awọn ipinlẹ mọkanlelogun ninu mẹrindinlogoji to wa ni Naijiria.
Nipa ilana inawo si eto yii, ijọba apapọ lo n ṣagbatẹru owo ti wọn fi n pese ounjẹ ọfẹ naa, wọn si n gba awọn alasẹ to n se e, bo tilẹ jẹ pe awọn iṣoro kan pada jade nigba ti awọn ipinlẹ kan fẹsun kan ijọba pe wọn ko kowo kalẹ fun eto naa mọ.
Bakan naa ni eto yii koju iṣoro nipa itẹsiwaju rẹ.
Ọrọ nipa ikowo rẹ jẹ bẹrẹ si I jade, a gbọ nipa awọn alase to n ko ounjẹ tutu pamọ fun jijẹ ati tita tiwọn, ati ai si abojuto ati akọsilẹ nipa bo ṣe n lọ.
Bẹẹ naa si ni awọn awoye kan bu ẹnu atẹ lu eto ounjẹ yii patapata, wọn ni ipa ki lo ni lara akẹkọọ ti ko ni yara ikawe, ati awọn ti ko si nnkan amayedẹru kankan nileewe wọn.
Ibeere ti ọpọ eeyan n beere lori igbesẹ ounjẹ ọfẹ ti ijọba fẹẹ gbe yii ni pe njẹ yoo si kẹsẹjari lọtẹ yii bi?
Eyi ri bẹẹ pẹlu bi wọn ṣe foju wo o pe ṣe ẹẹdẹgbẹta naira naa lo niye lori to bẹẹ, ti yoo to lati fi bọ ọmọ kan.
Koda, bi wọn pada gbe e si ẹgbẹrun kan naira, aridaju wo lo wa pe ijọba yoo fi pese ounjẹ aṣaraloore ti wọn n fẹẹ gunle yii.
Ero awọn ẹlomi-in ni pe eyi kọ ni igba akọkọ ti ijọba apapọ yoo kede ounjẹ ọfẹ, to si jẹ pe akude maa n de ba a laaarin kan ni.
Wọn ni nigba ri wọn bẹrẹ eto naa laye ijọba Buhari, bi wọn ṣe pin ṣibi ni wọn pin abọ ijẹun fun awọn akẹkọọ, paapaa lapa Ariwa, ṣugbọn o pada foriṣanpọn ni.
Ṣugbọn boya ti eyi ti iṣakoso ọtẹ yii fẹẹ bẹrẹ ni 2026 yoo yato si ti tẹlẹ ni ẹnikan ko ti i le sọ.