Ìjọba Nàìjíríà ṣe àgbékalẹ̀ ìlànà ìkẹ́kọ̀ọ́ tuntun fáwọn akẹ́kọ̀ọ́
Fẹ́mi Akínṣọlá
Iléeṣẹ́ tó ń rí sí ètò ẹ̀kọ́ ní Nàìjíríà tó fi ìkéde náà síta ní, èròńgbà wà pé ìlànà ìkẹ́kọ̀ọ́ tuntun yóò mú àdínkù bá iye iṣẹ́ táwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ń kọ́ àti pé yóò túnbọ̀ fún wọn láàyè láti kẹ́kọ̀ọ́ tó péye.
Nínú àtẹ̀jáde tí Mínísítà kejì fún ètò ẹ̀kọ́, Ọ̀jọ̀gbọ́n Suwaiba Ahmad fi léde, ó ní àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kò ní máa ṣe iṣẹ́ púpọ̀ ní kíláàsì tó sì jẹ́ pé ohun tí wọ́n yóò máa kọ́ yóò fẹsẹ̀ múlẹ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.
Àtúnṣe ètò ẹ̀kọ́ yìí ló ń wáyé ní àkókò tí èsì ìdànwó àṣekágbá ilé ẹ̀kọ́ girama, ìyẹn Senior Secondary School Certificate Examination (SSSCE) tí àjọ West Africa Examination Council ṣe àkọọ́lẹ̀ èsì ìdánwò tó burú jùlọ.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Ahmad sọ pé gbogbo àwọn lóókọlóókì lẹ́ka ètò ẹ̀kọ́ tó fi mọ́ Nigerian Educational Research and Development Council (NERDC), Universal Basic Education Commission (UBEC), National Senior Secondary Education Commission (NSSEC), National Board for Technical Education (NBTE) àtàwọn ẹ̀ka míì tí ọ̀rọ̀ kan ni wọ́n jẹ ṣe àtúnṣe náà.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àjọ náà kò sọ pàtó ìgbà tí ìlànà tuntun yìí yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ́ àmúlò, wọ́n ní àwọn máa ṣe àmójútó rẹ̀ láti ri dájú pé gbogbo àwọn ilé ẹ̀kọ́ káàkiri Nàìjíríà ló tẹ̀lé gbogbo ìlànà ọ̀hún bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.
Nínú ìlànà tuntun náà, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti ìpele ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ kìíní sí ipele kẹta (pry 1-3), àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yóò máa ṣe iṣẹ́ mẹ́sàn-án sí mẹ́wàá. Àwọn iṣẹ́ tó ṣe kókó tí wọ́n yóò sì máa ṣe ni ìmọ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ìṣirò, sáyẹ́ńsì àti ìmọ̀ ẹ̀rọ, àṣà, ìmọ̀ àtinúdá, ẹ̀sìn àti èdè Nàìjíríà kan.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ìpele kẹrin sí ìkẹfà yóò máa ṣe iṣẹ́ mẹ́wàá sí méjìlá tí àwọn iṣẹ́ tí wọ́n máa ma ṣe sì jẹ́ ìmọ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ìṣirò, sáyẹ́ńsì àti ìmọ̀ ẹ̀rọ, àṣà, ìmọ̀ àtinúdá, ẹ̀kọ́ṣẹ́ ọwọ́, ìmọ̀ ẹ̀sìn àti èdè Nàìjíríà kan.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti ipele ilé ẹ̀kọ́ girama ọdún mẹ́ta àkọ́kọ́ yóò máa ṣe iṣẹ́ méjìlá sí mẹ́rìnlá tó fi mọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì, ìṣirò, sáyẹ́ńsì àti ìmọ̀ ẹ̀rọ, àṣà, ìmọ̀ àtinúdá, ẹ̀kọ́ṣẹ́ ọwọ́, èdè Fransé, ìmọ̀ ẹ̀sìn àti èdè Nàìjíríà kan.
Nígbà tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti ipele girama mẹ́ta tó kẹ́yìn yóò máa ṣe iṣẹ́ mẹ́jọ sí mẹ́sàn-án tó fi mọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì, ìṣirò, ìmọ̀ nípa ojúṣe ẹni, okoòwò, àti ìmọ̀ ẹ̀rọ.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ẹ̀kọ́ṣẹ́ ọwọ́ yóò máa ṣe iṣẹ́ mẹ́sàn-án sí mọ́kànlá.
Alága àwọn olùkọ́ ní ìpínlẹ̀ Kwara, Agboola Yusuf sọ fún akọ̀ròyìn pé òun ní ìgbàgbọ́ pé àtúntò yìí yóò so èso rere fún ètò ẹ̀kọ́ Nàìjíríà.
Yusuf wòye pé ohun tó ṣe pàtàkì jùlọ ni pé kí wọ́n ṣe àmúlò àwọn nǹkan tí wọ́n fẹnukò lé lórí nípa àtúntò náà láti le jẹ́ kó kẹ́sẹ járí.
Ó ní ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí àtúntò ń wáyé lẹ́ka ètò ẹ̀kọ́ àmọ́ tí kò ní sí àmúṣẹ rẹ̀ tó bó ṣe yẹ.
“Ohun tí wọ́n ń pè ní àtúntò ìlànà ìkẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti máa ṣiṣẹ́ lé lórí kó tó di pé wọ́n gbe kalẹ̀, ó dámi lójú pé nǹkan dáadáa ló máa jáde níbẹ̀.
“Ohun tó kàn ṣe pàtàkì ni pé báwo ni ṣe máa ṣe àmúṣẹ àwọn àtúntò náà tó fi jẹ́ pé ohun tí wọ́n fi sùn máa wá sí ìmúṣẹ.”
Ní ọdún 2011 ni iléeṣẹ́ ètò ẹ̀kọ́ ti ṣe àtúntò àwọn ètò ẹ̀kọ́ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ girama gbẹ̀yìn nígbà tí ti àwọn ti ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ sì wàyè lọ́dún 2014.
Àjọ NERDC lọ́dún 2014 ṣe ìfilọ́lẹ̀ àtúntò ìlànà ètò ẹ̀kọ́ ọlọ́dún mẹ́sàn-án fún ètò ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ tí wọ́n pè ní Basic Education Curriculum (BEC).
Nígbà náà ni wọ́n ṣe àgbéjáde àwọn iṣẹ́ bíi ìmọ̀ sáyẹ́ńsì kan, ìmọ̀ ẹ̀rọ àti ìmọ̀ kọ̀mpútà síta èyí tó jẹ́ kí iṣẹ́ táwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ń ṣe fi wọ ogún.
Ní ọdún 2024, Mínísìtà tẹ́lẹ̀ rí fún ètò ẹ̀kọ́, Ọ̀jọ̀gbọ́n Tahir Mamman kéde pé àwọn máa ìlànà tuntun míì jáde fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ girama.
Láti ìgbà náà ni àwọn àyípadà àti àtúntò ètò ẹ̀kọ́ ti ń wáyé. Lọ́dún 2024, iléeṣẹ́ ètò ẹ̀kọ́ ṣe àgbéjáde ìlànà ìkẹ́kọ̀ọ́ mẹ́ẹ̀dógún míì síta tó ní i ṣe pẹ̀lú okoòwò tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ àmúṣe rẹ̀ ní oṣù kìíní ọdún 2025.
Mínísítà tẹ́lẹ̀ rí náà sọ pé ìlànà tuntun náà wáyé láti ri dájú pé wọ́n ń pèsè àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó lé dá dúró fúnra wọn láti ipele ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀.
Àwọn ètò ẹ̀kọ́ náà ló fi mọ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ Digital Literacy, ìkẹ́kọ̀ọ́ ṣíṣe omi, aṣọ ṣíṣe, ilé kíkọ́, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ó ní èyí yóò fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ní àǹfàní láti ní ìmọ̀ tó pọ̀ èyí tí yóò ṣe atọ́nà wọn láti mú ọ̀kan ní òkúnkúndùn, tí wọ́n máa yàn láàyò lọ́jọ́ iwájú.
Lọ́dún 2025, Mínísítà fún ètò ẹ̀kọ́ Nàìjíríà, Tunji Alausa pè fún lílo ètò ẹ̀kọ́ ọlọ́dún méjìlá sí ọdún mẹ́rin dípò ọlọ́dún mẹ́sàn-án, mẹ́ta àti mẹ́rin tí Nàìjiríà ń lò tẹ́lẹ̀.