Ìjọba Makinde fẹ́ yá 300Bn awuyewuye sọ
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn àgbà sọ pé bí èèyàn bá dákẹ́, dájúdájú ti ara rẹ̀ yóó bá dákẹ́ bóyá èyí náà ló fàá,
láti bí ọjọ́ mélòó kan báyìí tí ẹnu fi ń bẹ̀rẹ̀ sí ní kun ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àti ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, nítorí 300bn náírà tí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin náà buwọ́lù fún Gómìnà Ṣéyì Mákindé láti yá.
Ọkan lara ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ to n ṣoju ẹkun idibo Iwọ-oorun Ṣaki, to tun jẹ aṣoju ẹgbẹ oṣelu APC, Họnọrebu Ibraheem Shittu lo kọkọ pariwo sita lori ayelujara Facebook wi pe, oun ko si ni ibi ti ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ ti buwọlu ẹyawọ ọọdunrun biliọnu Naira fun Gomina Ṣeyi Makinde.
Shittu ni iyalẹnu nla ni igbesẹ naa jẹ fun oun nitori pe ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ wa l’ẹnu isinmi ọlọsẹ mẹfa nigba ti oun gbọ iroyin nipa ẹyawo naa.
O fi kun ọrọ rẹ wi pe ipade pajawiri kan ni awọn alakoso ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ sare ṣe ki wọn le fun Makinde ni anfaani lati ya owo naa lai fi ọrọ to awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin to ku leti.
Ibeere ti Họnọrebu yii wa n beere ni pe, “ki lo de ti ijọba ipinlẹ Ọyọ tun fẹ lọ ya owo nigba to jẹ wi pe aleekun ti ba iye owo ti ijọba apapọ n fun un pẹlu ilọpo ẹẹdẹgbẹta?”.
Bakan naa lo tun n beere wi pe ki lo de ti awọn alakoso ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ ko fi ọrọ to awọn ọmọ ile igbimọ naa leti ki wọn to buwọlu ẹyawo naa.
Lẹyin ọrọ ti Họnọrebu Shittu fi lede lori Facebook ni ọkanojọkan ariwisi ti n waye lori ọrọ naa.
Eyii lo mu ki ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ fesi ninu atẹjade kan ti adari ọmọ ẹgbẹ oṣelu to pọ ju nile igbimọ aṣofin naa, Hon. Sanjo Adedoyin ati alaga igbimọ ile to n ri si ikede, iroyin ati ọrọ to niiṣẹ pẹlu ẹrọ igbalode, Hon. Waheed Akintayo (Ilumoka) buwọlu, ti wọn si fi ranṣẹ si awọn akọroyin.
Atẹjade naa tọka rẹ wi pe ọrọ ti Họnọrẹbu Shittu fi lede jẹ ọrọ to n ṣini lọna ti o si tun fi han wi pe Họnọrebu naa ko mọ ojuṣe rẹ.
Bakan naa ni wọn sọ siwaju sii wi pe gbogbo ọmọ ile igbimọ aṣofin naa ni awọn sọ fun wi pe ipade pajawiri kan yoo waye lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkandinlogun oṣu Kẹjọ ọdun yii.
O ni awọn fi ikede sita ni oju opo Whatsapp ti ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ n lo.
Bakan naa ni wọn ya aworan atẹjiṣẹ ti wọn fi ranṣẹ si awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ lori ipade naa.
Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ tun ṣe alaye siwaju sii wi pe Họnọrebu Shittu to n fi ẹsun kan yii kii saba kopa nibi awọn ipade ti ile igbimọ aṣofin naa ba pe pẹlu alaye wi pe ida ogun pere ni iwọn bi o ṣe n kopa nibi awọn ipade ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ.
Wọn ni iwọsi nla gbaa ni isansa to n ṣe lẹnu iṣẹ rẹ n ko ba awọn eeyan ilu Ṣaki ti o n ṣoju nile igbimọ aṣofin.
Alaye ti ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ ṣe ninu atẹjade ti wọn fi ranṣe ni pe biliọnu mọkandinlaadọjọ Naira(N149Bn) ni ijọba ipinlẹ Ọyọ fẹ fi san lara gbesẹ ti wọn jẹ ile ifowopamọ UBA(United Bank for Africa).
Biliọnu mọkanlelaadọjọ(N151Bn) to ṣẹku yoo jẹ lilo fun ipese awọn ohun elo amayedẹrun ati lati san owo iṣẹ fun awọn agbaṣẹṣe ti ijọba ipinlẹ Ọyọ gbe iṣẹ fun jakejado ipinlẹ Ọyọ.
Ninu oṣu kẹjọ ọdun 2021, ile igbimọ aṣofin buwọlu ẹyawo biliọnu mẹfa Naira(N6Bn) ti Gomina Makinde gba lati ṣe awọn akanṣe iṣẹ ilu.
Ninu oṣu Kẹwaa ọdun 2021 bakan naa, Makinde ya biliọnu mejidinlogun Naira mii.
Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ tun buwọlu ẹyawo aadọjọ biliọnu Naira(N150Bn) fun Gomina Makinde ninu oṣu Kinni ọdun 2024.
Laarin ọdun 2025 taa wa yii, ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ ti buwọlu ẹyawo igba biliọnu Naira(N200Bn) ninu oṣu Kẹta, wọn tun fi ontẹ lu ẹyawo aadọfa biliọnu Naira(N110Bn) ninu oṣu Keje, ko to di pe wọn pe ipade pajawiri lati buwọlu ẹyawo ọọdunrun Billiọnu Naira(N300Bn) ninu oṣu kẹjọ ọdun taa wa yii.