Ìjọba Kwara gbé àgọ́ Àgùnbánirọ̀ lọ sí Kwara Poly
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣe àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní ohun tí a kò bá fẹ́ kó bàjẹ́, ó ní bí wọ́n ti í ṣe é.
Lójúnà àti dènà ikọlù láti ọwọ́ àwọn agbébọn tó ń da àwọn agbègbè kan láàmú ní ìpínlẹ̀ Kwara, ìjọba ìpínlẹ̀ náà ti gbé àgọ́ Àgùnbánirọ̀ tó wà ní Yikpata, níjọba ìbílẹ̀ Edu, kúrò níbi tó wà, wọ́n gbé e lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Kwara Poly, Ilorin.
Alaboojuto ajọ NYSC ni Kwara, Joshua Onifade, sọ eyi di mimọ l’Ọjọbọ ana, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹsan-an ọdun 2025.
Onifade fidi iṣipopada agọ naa mulẹ lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ n’Ilorin, pẹlu alaye pe ijọba gbe igbesẹ naa lati ṣẹgun idunkooko awọn agbebọn lagbegbe Yikpata ti agọ naa wa tẹlẹ.
O fi kun un pe aabo awọn agunbanirọ jẹ ijọba logun lo mu ki wọn gbe agọ naa lọ ojuna Jebba atijọ, nibi ti ile ẹkọ Poli Ilorin wa.
“Awọn alaṣẹ ajọ NYSC n dupẹ lọwọ ijọba ipinlẹ Kwara ati awọn ẹṣọ alaabo lati ṣẹgun iṣoro eto aabo.
“Bi wọn ṣe agọ yii kuro wa fun ki ọkan awọn agunbanirọ to ba n bọ le balẹ. Paapaa julọ, awọn ti wọn n bọ ni Kwara fun igba akọkọ.”
Alabojuto ajọ NYSC ni Kwara lo ṣalaye bẹẹ.
O gboriyin fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq, fun gbigbe igbesẹ to le dena ikọlu.
Gẹgẹ bo ṣe wi, Agunbanirọ 1,800 ni wọn n reti lati sinru ilu ni Kwara fun ti saa ọdun 2025 yii, isọri B.
Ọjọ kerinlelogun oṣu Kẹsan-an yii ni eto naa yoo si bẹrẹ kaakiri Naijiria.
Tẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni awọn iroyin ikọlu awọn agbebọn kan bẹrẹ si i wa lati ipinlẹ Kwara.
Iroyin naa ṣalaye bi awọn akọluni naa ṣe bẹrẹ lati ilu kan ti wọn n pe ni Ganmu Ahileru, ti wọn wọle pa awọn eeyan ti wọn si n gbe awọn miran lọ.
Bakan naa ni ilu kan ti wọn n pe n Baba Nla, koju awọn agbebọn laipẹ yii. Wọn pa eeyan, wọn si tun gbe awọn kan lọ, bẹẹ ni wọn n beere ọgbọn miliọnu naira owo itusilẹ.
Awọn eeyan ilu Patiki naa ko gbẹyin ninu ilu ti awọn agbebọn ti ṣọṣẹ, ti wọn pa baba ati ọmọ, to bẹẹ ti araalu n rawọ ẹbẹ pe ki ijọba ba awọn rọjo ado oloro si ibuba awọn ajinigbe naa to wa ninu igbo kan niluu naa.
Bo si tilẹ jẹ pe ijọba ni ko si ilu to di ahoro nitori ikọlu, awọn fidio kan to gba ori ayelujara kan, ṣafihan aisi ohunkohun niluu naa mọ, titi kan awọn nnkan ọsin.
Ọsẹ to kọja lọhun-un ni awọn ọdọ ilu Isanlu-Isin, nipinlẹ Kwara kan naa, ṣewode tako ikọlu to sọ eeyan meji di awati, ti ọkada mẹẹẹdọgbọn to jẹ ti awọn fijilante si ṣe bẹẹ jona lati ọwọ awọn agbebọn bi wọn ṣe sọ
L’Ọjọru ọsẹ yii, iroyin sọ pe fijilante kan padanu ẹmi rẹ, nigba ti awọn agbebọn yawọ Abule Kakafu, nijọb ibilẹ Patigi, ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ.
Awọn agbebọn naa ṣina ibọn bole, fijilante ti wọn pe orukọ rẹ ni Tetengi naa ni wọn lo jade lati koju wọn, nibẹ ni wọn si ti yinbọn fun un, to ku.
Araalu naa kan ti ko darukọ rẹ, sọ pe inu ibẹru ni awọn n gbe.
O ni afi ki ijọba tete dide si ọrọ ai si aabo yii, nitori ko si ifọkanbalẹ fun araalu mọ.
Awọn agbegbe ti ikọlu naa n kan ju bi a ṣe gbọ ni Patigi, Edu ati Kaiama .
Ni ti agọ Agunbanirọ ti wọn ṣi nipo pada yii, ijọba Kwara ti ko awọn ẹṣọ alaabo sibẹ lati mojuto bo ṣe n lọ lasiko eto ọlọsẹ mẹta ti yoo waye nibẹ.
Ki wọn si kapa ohunkohu to ba fẹẹ di alaafia ibẹ lọwọ.
Gbogbo igbiyanju lati ba agbẹnusọ ijọba ipinlẹ Kwara, Mallam Rafiu Ajakaiye, sọrọ lori iṣẹlẹ yii, ni ko kẹsẹ jari.
Bakan naa ni agbẹnusọ NYSC ni Kwara, Oladipo Morakinyo, ko fesi si ibeere wa.