Ìjọba ìpínlẹ̀ Ekiti fi N100M ṣe ìrànlọ́wọ́ f’áwọn tó ní ìjàm̀bá iná
Láti Ìròyìn òwúrọ̀
Ijọba ipinlẹ Ekiti lawọn ti se iranlọwọ ti ko din ni miliọnu lọna ọgọrun-un (N100M) fun awọn olufaragba ijamba ina laarin ọdun kan, pẹlu ẹbun (N35M) milionu marundinlogoji fun awọn olufaragba iṣẹlẹ tuntun.
Igbákejì Gómìnà, Arábìnrin Monisade Afuye, sọ èyí ní ọjọ́ ìṣẹ́gun ní Ado-Ekiti, nígbà tí ó ń pín iwe sowedowo fún abala kejì àwọn tí o ni ijamba iná ni ìpínlẹ̀ náà.
Afuye sọ pé ìjọba náà ná owó tó tó (N150M) mílíọ̀nù aadọjọ láti dín ipa òjò ọdún 2025 lórí àwọn tí wọ́n farapa láti àwọn ìgbìmọ̀ ìjọba mẹ́rìndínlógún kù.
Ó ní Gómìnà Biodun Oyebanji se ibanikedun fun àwọn tí wọ́n farapa nígbà tí wọ́n pàdánù dúkìá owo iyebiye ti ko se fenu sọ sinu ijamba ina naa.
Ó rọ àwọn tó gba iranlọwọ náà láti lo owó náà dáadáa kí wọ́n sì túbọ̀ ṣọ́ra láti lè gbé ìgbésẹ̀ láti dènà irú ìṣẹ̀lẹ̀ búburú bẹ́ẹ̀.
“Ìjámbá iná jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìbànújẹ́ tó burú jùlọ tí ẹnikẹ́ni tàbí ìdílé lè ní.”
“Láàárín ìṣẹ́jú díẹ̀, ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àṣekára laimọye ọdun, ìdókòwò àti àwọn ìrántí tí a fẹ́ràn lè di eérú.”
“Kò sí iye owó tí a fún yin tó lè rọ́pò ohunkóhun tí ẹ ti pàdánù, ṣùgbọ́n gómìnà gbàgbọ́ pé ìdásí yìí yóò fún yin ní ìtura díẹ̀, yóò sì ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìṣírí fún ìpadàbọ̀sípò, àtúnkọ́ àti ìsọdọ̀tun ìrètí.”
“A ó rántí pé àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ búburú kan náà ṣẹlẹ̀ ní ọdún 2025 gba owó tó ju (N50M) aadọta mílíọ̀nù lọ láti ọ̀dọ̀ ìjọba ìpínlẹ̀ náà.”
“A retí pé àwọn tó ń jàǹfààní náà yóò lo ìrànlọ́wọ́ yìí pẹ̀lú ọgbọ́n láti tún gbé ìgbésí ayé wọn kalẹ̀ kí wọ́n sì tún ní ìdúróṣinṣin,” Afuye salaye.
Ó rọ àwọn ará ìlú láti ṣọ́ra kí wọ́n sì gba àwọn àṣà ààbò ní ilé wọn, ọjà àti ibi iṣẹ́ wọn.
Ó fi dá àwọn ará ìlú lójú pé ìjọba yóò máa tẹ̀síwájú láti mú kí àwọn ìlànà ìtọ́jú pajawiri lágbára sí i, yóò sì mú kí ìmọ̀ gbogbo ènìyàn nípa ìdènà iná àti àwọn ọ̀nà ààbò pọ̀ sí i.
Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀, Olùdarí Àgbà, State Emergency Management Agency (SEMA), Ọ̀gbẹ́ni Oludare Asaolu, sọ pé ìjọba tí Oyebanji ń darí ń parí ìjíròrò láti fọwọ́ sí ìwé àdéhùn pẹ̀lú Ilé Iṣẹ́ Ìṣàkóso Pajawiri ti Ìpínlẹ̀ Eko fún àwọn ohun èlò àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àwọn òṣìṣẹ́ iná ti ìpínlẹ̀ náà.
Asaolu dupe lowo gomina fun iranwọ kiakia ni ipinle naa.
Gẹ́gẹ́ bí ó ti salaye, èyí ló fà á tí wọ́n fi ń ṣe ìrànlọ́wọ́ nígbà gbogbo láti dín ìyà àwọn tí wọ́n ba dúkìá wọn jẹ́ kù.
Bákan náà, olórí ile iṣẹ́, National Emergency Management Agency ní Ekiti àti Ondo, Dókítà Kofoworola Soneye, gba SEMA àti àwọn mìíràn nímọ̀ràn láti mú kí àwọn ìpolongo ààbò wọn lágbára síi láti ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti gbé ìgbésẹ̀ láti ṣàkóso àwọn isẹlẹ pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ náà.









