Ìjọba fòfin de ìgbésẹ̀ Awujalẹ tuntun

Ìjọba fòfin de ìgbésẹ̀ Awujale tuntun

Yínká Àlàbí

Ijọba ipinlẹ Ogun ti se idalọwọkọ fun igbesẹ lati jẹ́ oye Oba Awujale ti Ijebu miiran.
Orisiirisii iwe enini lo ti kọja lọ si ile ẹjọ ti awọn miiran kọja lọ si ọdọ ijọba ipinlẹ Ogun lori oye naa.
Oni ọjọ wẹside, ọjọ kọkanlelogun osu kin-in-ni ọdun yii ni kọmisọna ijọba ibilẹ, Ọgbẹni Ganiyu Hamzat sare kọ iwe si awọn afọbajẹ ati idile Fusengbuwa ti oye ọba kan pe ki wọn duro.
Kọmisọna salaye pe “ipo ọba Awujale o ki n se ipo oye kekere nilẹ yii ati loke okun, nipa idi eyi, ijọba ko ni laju rẹ silẹ ki talubọ ko sii. Iwe enini ti pọ lori ipo ọba naa. Ijọba ipinlẹ Ogun ko si ni fi aaye gba jagidijagan rara”.
Igbakeji alaga idile tọba kan, Ọjọgbọn Fassy Yusuf ati Alaga idile naa Otunba Abdulateef Owoyemi jẹrii si idaduro naa.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here