Ìjọba àpapọ̀ fẹ́ fi ₦712bn ṣe pápákọ̀ ọkọ̀ òfurufú Èkó, ariwo ńlá gbòde

Ìjọba àpapọ̀ fẹ́ fi ₦712bn ṣe pápákọ̀ ọkọ̀ òfurufú Èkó, ariwo ńlá gbòde

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé àwọn àgbà ní bí ọrọ nlá kò bá tíì tán èèyàn nlá kò ní-ín sinmi àròyé bẹẹ lọrọ rí bó ṣe jẹ pé
láti ìgbà tí ìjọba àpapọ̀ ti kéde pé òun buwọ́lu ₦712 billion láti fi ṣe àtúnṣe pápá kọ òfurufú Murtala tó wà n’Ikeja, ìpínlè Èkó, ni awuyewuye ti bẹ̀rẹ̀.

Minisita to n ri si irinajo afẹ, Festus Keyamo, lo kede l’Ọjọbọ to kọja, lẹyin ipade igbimọ awọn alaṣẹ, pe aarẹ ti buwọ lu owo naa.

Keyamo ṣalaye pe eyi ni atunṣe akọkọ to jẹ gboogi, lati igba ti wọn ti kọ papakọ ofurufu naa.

O fi kun un pe ki papakọ ofurufu yii le da bii awọn ẹlẹgbẹ rẹ lagbaaye ni ijọba ṣe fẹẹ tun un ṣe pẹlu 712bn.

Ṣugbọn ọpọ eeyan lo n sọ pe lasiko ti ebi n pa araalu, ti ọrọ aje dẹnukọle ni ijọba fẹẹ ko owo nla bẹẹ si ori papakọ ofurufu.

Ni itẹsiwaju alaye ati awijare rẹ nipa atunṣẹ papakọ ofurufu naa, Keyamo to jẹ agbẹjọro agba lorilẹ ede Naijiria, ṣalaye lọjọ Aiku ọsẹ yii pe
‘ Ki i ṣe pe a ya owo sọtọ fun atunṣe naa lati ara owo eto iṣuna Naijiria, awọn owo ti a n ri lati ara eto Ireti ọtun, Renewed Hope Infrastructural Funding, (to jẹ opo awọn nnkan ti Aarẹ Bola Tinubu sọ pe oun yoo ṣe fun araalu), ni a maa lo fun un.

“O ti le logoji ọdun ti wọn ti kọ papakọ ofurufu yii, gbogbo ẹ lo ti dógùn-ún.

“Orule rẹ ti n jo, gbogbo ibẹ lo ti di akọti to si n rùn, gbogbo ori aja naa lo ti n ya lulẹ, iru rẹ ko si si lọja mọ lasiko yii.

“Ẹ tun maa ri awọn eeyan ti wọn kọ isọ oriṣiiriṣii kaakiri ti wọn n ta n ta ọja nibẹ.

” Ijọba yii ṣeleri igbedide awọn nnkan amayedẹrun fun araalu, lara owo ti a n ri ko jọ lati ara sọbsidi ti a yọ kuro ati igbedide owo naira la maa lo.

”O maa gba wa to oṣu mejilelogun ka too pari ẹ.”

Bẹẹ ni Minisita to n ri si ọrọ irinajo afẹ naa ṣalaye.

O fi kun un pe bijọba ko ba tun papakọ ofurufu yii ṣe, ọpọ ileeṣẹ ọlọkọ ofurufu ni yoo kọ Naijiria ti.

Keyamo sọ pe awọn ileeṣẹ naa yoo maa bẹru, nitori bi ọna to wọ papakọ ofurufu ko ba daa, wọn yoo maa ro pe gbogbo awọn nnkan yoku naa ko daa ni.

O ni Papakọ ofurufu Murtala Muhammed yoo maa figagbaga pẹlu awọn bii ti Ethiopia, South Africa ati awọn mi-in lagbaaye ni lẹyin atunṣe naa.

“Ki i ṣe atunṣe apa kan lasan, a n tu u palẹ pata ni. Awọn opo nikan lo ku to maa duro, a dẹ maa bẹrẹ atunkọ lẹsẹkẹsẹ.”
Ọkan lara awọn to tako igbesẹ ijoba apapọ ni ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC), wọn n beere pe njẹ ile igbimọ aṣofin buwọ lu owo gọbọi naa.

ADC sọ pe inakuna ati ai ka araalu kun ni eyi jẹ.

Atẹjade ADC ti Akọwe apapọ wọn, Bolaji Abdullahi, fi sita lọjọ Aiku, ṣalaye pe iru inawo yii fi han pe ijọba Tinubu ko ka inira awọn ọmọ Naijiria si nnkan kan, ati pe APC ko mọ pe iya n jẹ araalu.

” Ki i ṣe papakọ ofurufu alarabara ni ẹka irinna ofurufu nilo bayii, abojuto gidi lo yẹ.

” O ṣoro lati jẹ ko ye wa pe ₦712 billion ni wọn maa fi tun papakọ ofurufu ti ko pẹ ti wọn tun un ṣe lẹẹkan si i.

“Ni orilẹede ti gbogbo ohun amayedẹrun ko si, ti awọn olukọ fasiti da iṣẹ silẹ, ti ko si eto ilera gidi ni wọn ti fẹẹ kowo le papakọ ofurufu.

“Ko si nnkan kan to ṣe papakọ ofurufu Murtala Muhammed”

Bẹẹ ni apa kan atẹjade ADC wi.

Ṣugbọn pẹlu ariyanjiyan to gbode yii, ohun to foju han ni pe pe ₦712 billion yoo bẹrẹ iṣẹ atunṣe ti won ni wọn fẹẹ fi ṣe ni papakọ ofurufu naa laipẹ.