Ìjọba àpapọ̀, àwọn ìpínlẹ̀ gbé ilé ẹ̀kọ́ tìpa nítorí ìkọlù àwọn ajínigbé

Ìjọba àpapọ̀, àwọn ìpínlẹ̀ gbé ilé ẹ̀kọ́ tìpa nítorí ìkọlù àwọn ajínigbé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní n tí a kò bá fẹ́ kò bájẹ́, ó ní bí a ti i ṣe é.
Ìjọba àpapọ̀ àtàwọn ìpínlẹ̀ kan lẹ́kùn àríwá Nàìjíríà ti pàṣẹ gbígbé àwọn ilé ẹ̀kọ́ kan tìpa látàrí ìpèníjà ààbò àti báwọn ajínigbé ṣe ń jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbé.

Bí ìjọba àpapọ̀ ṣe gbé àwọn ilé ẹ̀kọ́ mọ́kànlélógójì tìpa náà ni àwọn gómìnà ní ìpínlẹ̀ Kwara, Plateau, Niger, Benue àti Katsina náà ti dá ètò ẹ̀kọ́ dúró láwọn ilé ẹ̀kọ́ kan fún ìgbà kan ná.

Ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kọkànlélógún, oṣù Kọkànlá, ọdún 2025 ni inú fu àyà fu tún bẹ̀rẹ̀ nígbà tí àwọn agbébọn tún ṣe ìkọlù sí ilé ẹ̀kọ́ St Mary Catholic School ní ìlú Papiri, ìjọba ìbílẹ̀ Agwara, ìpínlẹ̀ Niger.

Níbi ìkọlù náà ni àwọn ajínigbé ọ̀hún ti jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 215 àtàwọn olùkọ́ méjìlá gbé lọ.
Ìkọlù àwọn agbébọn yìí ló ń wáyé lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́rin tí wọ́n jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n gbé lọ ní ilé ẹ̀kọ́ Government Girls Comprehensive Secondary Secondary School, Maga ní ìpínlẹ̀ Kebbi.

Bákan náà ló ń wáyé lẹ́yìn ọjọ́ kejì táwọn agbébọn ṣèkọlù sí ilé ìjọsìn CAC ní ìlún Eruku, níbi tí wọ́n ti jí ọ̀pọ̀ olùjọsìn gbé lọ táwọn agbébọn náà sì ti ń bèèrè fún ogún mílíọ̀nù náírà gẹ́gẹ́ bí owó ìtúsílẹ̀ fún ẹnìkọ̀ọ̀kan iye èèyàn mẹ́tàdínlógójì tí wọ́n jí gbé.

Àwọn ìkọlù yìí ló mú kí ìjọba àpapọ̀ àtàwọn ìjọba ìbílẹ̀ láti wá ọ̀nà láti mú àdínkù bá àwọn ìjínigbé yìí.

Ìjọba àpapọ̀ ti pàṣẹ pé kí wọ́n ti àwọn ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n máa ń pè ní unity school tìpa láti dènà ìkọlù àwọn agbébọn yìí.

Àtẹ̀jáde kan tí adarí ètò ẹ̀kọ́ girama ní iléeṣẹ́ tó ń rí sí ètò ẹ̀kọ́, Binta Abubakar ni wọ́n ti kéde ìgbésẹ̀ náà.

Lára àwọn ilé ẹ̀kọ́ tó máa wà ní títìpa ni FGGC Minjibir; FGA Suleja; FTC Ganduje; FGGC Zaria; FTC Kafanchan; FGGC Bakori; FTC Dayi; FGC Daura; FGGC Tambuwal; FSC Sokoto; FTC Wurno; FGC Gusau; FGC Anka; FGGC Gwandu; FGC Birnin Yauri; FTC Zuru; FGGC Kazaure; FGC Kiyawa; FTC Hadejia; FGGC Bida; FGC New Bussa; FTC Kuta Shiroro.

Àwọn míì ni FGC Ilorin; FGGC Omu Aran; FTC Gwanara; FGC Ugwolawo; FGGC Kabba; FTC Ogugu; FGGC Bwari; FGC Rubochi; FGGC Abaji; FGGC Potiskum; FGC Buni Yadi; FTC Gashau; FTC Michika; FGC Ganye; FGC Azare; FTC Misau; FGGC Bajoga; FGC Biliri; àti FTC Zambuk.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Niger náà ti kéde gbígbé àwọn ilé ẹ̀kọ́ táwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa ń sun ibẹ̀ ní ẹkùn Niger North tìpa fún ìgbà kan ná.

Ìkéde yìí ni wọ́n gbé jáde nínú àtẹ̀jáde tí akọ̀wé ìjọba, Alhaji Abubakar Usman fi síta lọ́jọ́ Ẹtì.

Bákan náà ni ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara tí kéde títi àwọn ilé ẹ̀kọ́ pa ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́rin ìyẹn ní Isin, Irepodun, Ifelodun àti Ekiti níbi tí ìkọlù àwọn agbébọn ti ń wáyé lemọ́lemọ́.

Ìpinnu yìí ló ń wáyé nínú ìkéde tí alága ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ìpínlẹ̀ Kwara, Yusuf Agboola fi síta.

Bẹ́ẹ̀ náà ni ìjọba ìpínlẹ̀ Plateau kéde títi àwọn ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ káàkiri gbogbo ìpínlẹ̀ náà nítorí ètò ààbò tó mẹ́hẹ.

Agbẹnusọ ètò ẹ̀kọ́ káríayé ní ìpínlẹ̀ náà, Richard Jonah sọ pé ìjọba gbé ìgbésẹ̀ náà láti wà ní ojú lalákàn fi ń ṣọ́rí nítorí ìkọlù tó ń wáyé láwọn ìpínlẹ̀ míì.

Ó ní àwọn gbé ìgbésẹ̀ náà láti dènà irúfẹ́ ìkọlù bẹ́ẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Plateau.

Ní ìpínlẹ̀ Katsina, ìjọba ti pàṣẹ pé kí wọ́n gbé gbogbo àwọn ilé ẹ̀kọ́ tó jẹ́ ti ìjọba tìpa títí di ìgbà kan ná.

Kọmíṣánnà ètò ẹ̀kọ́ ní Katsina, Yusuf Jibia sọ fún àwọn akọ̀ròyìn lọ́jọ́ Ẹtì pé ìgbésẹ̀ náà ń wáyé láti dá ààbò bo àwọn akẹ́kọ̀ọ́.

Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ń ṣe ìdánwò lọ́wọ́, dídá ààbò bo ẹ̀mí àti dúkìá ṣe pàtàkì, tí àwọn sì mú ní òkúkúdùn.

Jibia fi kun pé àwọn gbé ìgbésẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ ná láti ṣe àgbéyẹ̀wò ètò ààbò ìpínlẹ̀ náà.

Ẹ̀wẹ̀, agbẹnusọ ìjọba ìpínlẹ̀ Kebbi, Ahmed Idris sọ pé ìjọba ìpínlẹ̀ Kebbi ti pọn kún ètò ààbò àmọ́ wọn kò ní ti àwọn ilé ẹ̀kọ́ pa.

Idris ní bíi ọ̀sẹ̀ mẹ́ta sí mẹ́rin ló kù fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti parí sáà àkọ́kọ́ tí wọ́n ń ba lọ lọ́wọ́ àti pé ètò ààbò tí wọ́n ti là kalẹ̀ yóò jẹ́ kí ìtẹ̀síwájú bá ètò ẹ̀kọ́.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here