Ìjà àgbà méjì: Aláàfin ń gbéná wojú O̩o̩ni

Ìjà àgbà méjì: Aláàfin ń gbéná wojú O̩o̩ni

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà ní nǹkan súusùu lèsù ú sù.

Ohun kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn tún ń kọminú sí nínú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ni pé ṣé Aláàfin Ọ̀wọ́adé mọ̀ nípa àtẹ̀jáde onígbèdéke ọjọ́ méjìì ọ̀hún kó tó jáde láti kọ̀ bì ààfin.

Tabi pe ṣe Akọwe iroyin rẹ lo n da iṣẹ jẹ lọwọ ara rẹ pẹlu awọn ọrọ ti wọn lo tabuku to lo ninu atẹjade naa.

Ẹ o ranti pe laipẹ yii ni Alaafin Abimbola Owoade ba akọroyin sọro̩ ninu ifọrọwerọ to nibi to ti sọ pe idagbasoke ilu lo jẹ oun logun, to si fi da ilu loju pe oun ko ba ẹnikẹni ja àti pé ọmọluabi ni oun.

Kabiyesi Owoade sọ pe ija kankan ko si laaarin oun ati Ooni Adeyeye Ogunwusi.

O ni awọn eeyan to fẹẹ fi iroyin pawo sapo ara wọn lo fẹẹ da rugudu silẹ, ti wọn n gbe ohun ti ko ṣẹlẹ kiri.

Ọpọ eeyan nilẹ Yoruba lo ti n koro oju si atẹjade to ti aafin Oyo wa yii, ti ọrọ naa si n tan kalẹ si i.
Àwọn èèyàn gbà pé ipò ọba lagbara púpọ, bí wọn kò bá si tete gbé ìgbésẹ láti paná to tun fẹ rú yìí, o lè mu ìyapa to nipọn bá awujọ Yorùbá, bẹẹ,ifaseyin nla ni yóò jé bí wọn kò bá wà ojútùú sí ọrọ náà lójú ọjọ.
Àwọn mìíràn sọ pé àsìkò yí kìí ṣe ń tí àwọn akọroyin le máa bu bẹntiróòlù sí ọ̀rọ̀ tó n lo̩ lààrin àwọn ori adé méjì náà àti pé àsìkò nìyí tó
yẹ kí àwọn olùdámọ̀ràn wọn lórí ètò ìròyìn mọ n tí wọ́n n pè ní àṣà àti ìṣe Yorùbá yàtọ̀ sí pé wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ ìgbàlódé ní Fásitì.

Idahun ni awọn mi-in si n wa, si iyatọ to wa ninu Ọkanlo̩mo̩ Oodua ati Ọkanlọmọ ilẹ Yoruba, eyi si lo fadii aawo̩. Alaafin ni oye to ba ti ni nnkan se pe̩lu Yoruba lapapo̩ gbo̩do̩ wa lati aafin O̩yo̩, ko gbo̩do̩ je̩ lati Ile-Ife̩.
Jù gbogbo rẹ̀ lọ, ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ báyìí kìí ṣe awẹ́wa ,àwọn àgbà rere, ọmọ Yorùbá tòótọ́ ̣ gbọ́dọ̀ tètè jí gìrì sí iná ọ̀tẹ̀ tó fẹ́ ti ọ̀nà ẹ̀bùrú jó ìran Yorùbá yìí, nípaṣẹ̀ àwọn ọba alayé tó gbé àwòkọ́ṣe àṣà wa dáni.