Ìgbéyàwó mi kò dàrú – K1 De Ultimate

Ìgbéyàwó mi kò dàrú – K1 De Ultimate

Mary Fágbohùn

Ilumooka olorin Fuji, Ayinde Marshal, ti a mo si K1 De Ultimate, ti soro sita leyin aheso oro pe igbeyawo re pelu iyawo re, Emmanuella, ti ni idarudapo ninu

Eyi waye leyin ti olorin naa ko ifenukonu lati odo iyawo re ninu fonran aseye ojo ibi ti iyawo re fi se ohun iyalenu fun, fonran naa lo n kaakiri ori ayelujara.

Atejade yii ni Kunle Rasheed gbenu olorin naa so ni oju opo Instagram re ni ojo Isegun.

Gege bi ohun ti atejade naa so, olorin naa ati iyawo re si feran ara won pupo ti won ko si ronu pe awon fe fi opin si igbeyawo won ri.

Atejade naa ni o pe akole re ni, ‘K1, EMMANUELLA FA AHESO ORO PE IGBEYAWO WON NI IDARUDAPO LULE’, o ka bayi pe, “O ti de eti igbo wa pe aheso oro miiran ti ko lese nle n loo kaakiri pe Mayegun ti ile Yoruba, K1 De Ultimate ko nife iyawo re mo, nitori naa o ko ifenukonu to wa lati odo iyawo re nibi aseye ojo ibi iyalenu ti won se ni Radisson Blu ni opin ose to koja.

“Awon ontaja aheso yii ka ohun ti ko ni itumo si babara lori ohun ti won ro ni okan, o ye ki won se ajoyo ki won si tan oro naa kale lori ere ti ko ye wa.

“O je ohun to buru pe awon ti won n gbe oro naa kaakiri ko ri ohun gidi kan so dipo be e o ye ki won ri pe ife ti ri ibujoko titi lai ni okan aya tokotaya naa.

“O je ohun aridaju pe K1 ati iyawo re Emmanuella nife ara won gidi. Eyi ye ko ye opo eniyan, paapaa julo awon ti won n duro lati sajoyo lori irohin ibanuje nipa tokotaya.

“Opolopo awon alabosi yi ti gba pe ibasepo naa ko le e jora, lo wa ninu irora nigba ti won ri pe igbeyawo naa n gberu si i. O kun won pelu ibanuje ati inira to be e ge ti ise oojo won fi di pe ki won si ile itaja lati mu ki ailayo won ran tokotaya ti won n fi gbogbo igba gbadun ibasepo won.

“A nife lati so ni igba kewa pe, ‘Ajike Okin’ ati oko re K1 De Ultimate mo ona lati mu ki oju won wa lara itanna oorun, ki ojiji le e bo si eyin won. Won si wa ninu oko ife, to si n lo geere lori omi, ti won o si ronu pe ki oko naa ri sinu omi tabi ki won da oko naa duro. Kunle Rasheed lo bu owo lu u. (Fun K1 De Ultimate band).”

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here