Ìgbẹ́jọ́ Alfa Abdulrahman lóri ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ àti ikú Afsot Yetunde ní Ilorin , bàbá olóògbé Afsot bú sẹ́kún gbagada

Ìgbẹ́jọ́ Alfa Abdulrahman lóri ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ àti ikú Afsot Yetunde ní Ilorin , bàbá olóògbé Afsot bú sẹ́kún gbagada

Fẹ́mi Akínṣọlá ẹ́ẹ̀ ọ́ọ̀ ńǹ

Ìgbẹ́jọ́ Abdurahman Bello àti àwọn mẹrin mii tí wọ́n fẹ̀sùn ìpànìyàn àti ìfipá bánilòpọ̀ kan nípa akẹ́kọ̀ọ́ kan Afsot Yetunde ń tèsíwájú lónì í ọjọ ọjọ́rú , ọjọ keje oṣù kàrún ọdún 2025.

Ile ẹjọ giga ti ipinlẹ Kwara to wa ni ilu Ilọrin, tii se olu ilu ipinlẹ kwara ni igbẹjọ naa ti n waye eyi ti adajọ Christiana Ajayi n dari rẹ.

Awọn olujẹjọ maraarun ti wọn fi ẹsun ipaniyan naa kan, to fi mọ Alfa Abdulrahman, ni wọn farahan ni ile ẹjọ naa.

Losu to kọja lẹjọ naa bẹrẹ ni pẹrẹu lẹyin ọpọ ifaara to ti kọkọ waye saaju nile ẹjọ.

Adajọ si pasẹ pe ki wọn fiawọn afurasi naa si ahamọ ọgba ẹwọn Okekura ilu Ilọrin lẹyin ti wọn ka ẹsun ti wọn fi kan wọn tan.
Nigba ti igbẹjọ naa bẹrẹ laago mẹsan kọja isẹju mẹfa ni aarọ oni, Adajọ beere orukọ awọn agbẹjọro to yọju, ti wọn si darukọ ara wọn lọ kọkan.

Kọmisana feto idajọ ni ipinlẹ Kwara, Senior Ibrahim lo ko awọn agbẹjọro ijọba sodi .

Abubakar Yinusa ati F A , Yusuf,A N Oluwatoyin soju olujẹjọ kẹta àti ikẹrin.

H A, Fọlọrunshọ ati A A Abolaji Ajasa ati Ayara soju olujẹjọ keji.

Lẹyin eyi ni Adajọ pe ẹlẹri kini ti se SP Yusuf, ọlọpaa agbefọba lati ẹka to n sewadi iṣẹlẹ ọdaran lọfisi ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara.

Agbefọba sọ pe lọjọ kẹrindinlogun oṣu keji ọdun 2025 ni wọn mu gbogbo awọn afurasi naa fun ẹsun ipaniyan, idigunjale ati nini ẹya ara eeyan ni ikawọ wọn lọna aitọ.
Agbefọba naa sọ fun ile ẹjọ pe lara ohun ti awọn ri ni ile wọn awọn afurasi naa ni Ada, Ake, Rọba, Tabili ati ẹjẹ to wa ninu rọba.

Bakan naa, ọlọpaa naa ni awọn tun ri ẹrọ ibanisọrọ mẹrin, yẹti eti obirin, Iborun obirin, iwe oogun abẹnu gọngọ ti wọn kọ oogun ibilẹ ṣi ati iwo ẹranko ti wọn pe ni Olugbohun.

Gbogbo awọn eroja yii ni wọn ko wa si ile ẹjọ, ti adajọ si gba wọle gẹgẹ bi ẹri.

Agbẹjọro fawọn afurasi ni ki ẹlẹri sọ ọwọ ẹni to ti gba awọn nnkan to ko wa si ile ẹjọ, nitori ki se ọwọ gbogbo wọn ni wọn ti ba ikọọkan eroja naa.

Ẹlẹri naa ni ọpọ awọn nnkan ti wọn ko wa si ile ẹjọ, ni wọn ri gba lọwọ Abdurahman Bello to jẹ olori awọn afunrasi na.

Lẹyin na, adajọ pe ẹlẹri keji Wọle.
Eleri keji ni Inspector Muhammed lati ọọfisi ajọ ọlọpaa ipinlẹ Kwara.

O salaye fun ile ẹjọ pe awọn ri ẹya ara eeyan to jẹ ọwọ Ọtun, Ọwọ Osi, Ọkan eeyan lasiko iwadii wọn nile Alfa Abdulrahman Bello.

O ni afurasi Abdurahman Bello jẹ wọ fun awọn ọlọpaa pe ohun lo pa Afsot Yetunde naa.

Bakan naa, Muhammed ni lọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹrin ọdun yi ni Abdurahman mu awọn ọlọpaa lọ ibi ti wọn da ilẹ si.

O ni nibẹ ni wọn ti ri ẹya ara eeyan to ku, lẹyin naa lawọn ko ẹya ara eeyan naa lọ ile iwosan UITH ni Ilọrin, lati lọ tọju awọn ẹya ara naa, ko ma baa bajẹ.

Gbogbo ẹya ara eeyan naa si ni awọn ẹlẹri ko wa si ile ẹjọ loni.

Adajọ si gba awọn ẹya ara eeyan naa wọle gẹgẹ bi ẹri.
Ile ẹjọ tun pe ẹlẹri kẹta wọle, tii se Baba ti wọn pa, Ọgbẹni Ibrahim Lawal Adefolu.

Ọgbẹni Ibrahim Lawal ni Hasfot Lawal jade lọjọ kẹrindinlogun oṣu keji ọdun yii, ti awọn si wa pẹlu pipe ẹrọ ibanisọrọ rẹ ti kosi gbe.

Lẹyin eyi ni ẹrọ ibanisọrọ rẹ ko lọ mọ, ti awọn si gba agọ ọlọpaa lọ lati sọ fun wọn

O fikun pe, aarọ ọjọ Jimọ ni officer Moses pe awọn pe, ọwọ ti tẹ ọkunrin kan ti wọn pe orukọ ni Abdul-rahmon Bello.

Abdurahman Bello jẹwọ fun oun lagọ ọlọpaa pe oun ti sekupa Hafsoh Yetunde Lawal, ti oun si ti kun oku rẹ wẹlẹwẹlẹ.

Adajọ ni ki wọn gba ọwọ ati ẹya ara naa wọle, wọn si bi Baba Hasfot Lawal lere pe se ọwọ mejeji jọ ti ọmọ rẹ, o si ni bẹẹ ni, ọwọ Hasfot Lawal ni.

Adajọ gba ẹya ara naa wọle gẹgẹ bi ẹri.

Ẹlẹri kẹrin, Abdulazeez Falilat jẹ ọrẹ Hasfot Lawal.

Falilat salaye fun ile ẹjọ bi Hasfot Lawal se jade ni ile lọjọ to di awati, adajọ si gba ọrọ rẹ wọle gẹgẹ bi ẹri.

Lẹyin gbigbọ ọrọ lẹnu awọn ẹlẹri naa, adajọ sun igbẹjọ siwaju di ọjọ Aje ,ọjọ kejila osu karun ọdun yii.