Ìdúnàádúrà pẹ̀lú agbébọn jẹ́ ìwà ọ̀dàlẹ̀ sọ́mọ Nàíjíríà – Àwọn aṣòfin kan yarí

Ìdúnàádúrà pẹ̀lú agbébọn jẹ́ ìwà ọ̀dàlẹ̀ sọ́mọ Nàíjíríà – Àwọn aṣòfin kan yarí

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn aṣòfin kan nílé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin ti bu ẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ ìjọba Tinubu lórí ìlànà tó ń gbà kojú ìpèníjà ètò ààbò tó ń bá Nàìjíríà fínra.

Àwọn aṣòfin náà, láti ẹkùn mẹ́fẹ́ẹ̀fà tó wà ní Nàìjíríà, kọminú lórí ìpèníjà ààbò ṣe ń fi ojoojúmọ́ peléke síi àti bí àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣe ń wà nínú inú fu àyà fu lójoojúmọ́.

Àtẹ̀jáde kan tí wọ́n fi léde lọ́jọ́rú ni wọ́n ti bu ẹnu àtẹ́ lu ìlànà tí ààrẹ ń gbà kojú ìṣòro ààbò, tí wọ́n sì ní ààrẹ kò ṣe ojúṣe rẹ̀ bó ṣe yẹ.

Ṣáájú níbi ìjòkó ilé tó wá lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, àwọn aṣòfin fi ẹdùn ọkàn wọn hàn lórí ìpèníjà ààbò Nàìjíríà, tí wọ́n sì rọ ìjọba àpapọ̀ láti tètè wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá lórí ìpèníjà yìí.

Àwọn aṣòfin tí wọ́n kó ara wọn jọ náà bu ẹnu àtẹ́ lu bí ìjọba ṣe ń bá àwọn agbébọn jíròrò lórí ìkọlù tí wọ́n ṣe sáwọn akẹ́kọ̀ọ́.

Lára àwọn aṣòfin náà ni Muhammed Soba láti ẹkùn ìwọ̀ oòrùn àríwá, Zakari Mohammed láti ààrin gbùngbùn àríwá, Olasupo Abiodun láti gúúsù ìwọ̀ oòrùn, Sadiq Ibrahim láti ìlà òòrùn àríwá, Uko Nkole láti ìlà oòrùn gúúsù, àti Bassey Ewa láti ààrin gbùngbùn gúúsù.

Wọ́n wòye pé ṣíṣe ìdúnàádúrà pẹ̀lú àwọn agbébọn jẹ́ ìwà ọ̀dàlẹ̀ sáwọn èèyàn Nàìjíríà nítorí wọ́n ń bá àwọn ọ̀daràn jíròrò dípò kí wọ́n fi òfin gbé wọn.

Wọ́n ní kìí ṣe irú àsìkò yìí táwọn èèyàn Nàìjíríà ń sunkún lórí pípè fún ààbò tó péye ló yẹ kí ìjọba máa bá àwọn tó jí àwọn ọmọdé gbé, tí wọ́n ń ṣe ìkọlù sáwọn obìnrin láì bìkítà, tí wọ́n sì ń da ọ̀pọ̀ ìlú láàmú ló yẹ kí ìjọba máa bá jíròrò.
Nígbà tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ lórí ìkọlù tó wáyé ní Kano, Kwara, Kebbi, Niger àtàwọn ìpínlẹ̀ míì, àwọn aṣòfin náà níṣe ni ìjọba dákẹ́, tí wọ́n sì ń gba ọ̀nà ẹ̀yìn láti máa bá àwọn ọ̀daràn ṣe ìpàdé.

“Kò sí orílẹ̀ èdè tó ń ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ tó máa ma bá àwọn ọ̀daràn ṣe ìdúnàádúrà. Kò sí ibití bíbá àwọn agbébọn jíròrò ti so èso rere káàkiri àgbáyé, ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè tó ṣe bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kábàámọ̀ nígbẹ̀yìn.

“Ní Colombia, ìjíròrò tí ìjọba bá àwọn ikọ̀ Revolutionary Armed Forces mú àlékún bá ìjínigbé láti fi máa bèèrè owó, tó sì tún rọgun sápá àwọn ikọ̀ náà.

“Ní Afghanistan, ààyè tí wọ́n fi gba àwọn Taliban tó fi mọ́ pípàrọ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n ló fi ààyè gba àwọn ẹgbẹ́ láti gba ìjọba orílẹ̀ èdè náà.

Àwọn aṣòfin náà ṣèkìlọ̀ fún ìjọba àpapọ̀ láti yàgò fún bíba àwọn agbéṣùmọ̀mí jíròrò àti pé ìgbésẹ̀ náà yóò túnbọ̀ máa pọnkún ìwà ipá tó ń wáyé.

Wọ́n ní ìjọba ń sọ pé àwọn kò kajú òṣùwọ̀n, tí wọ́n sì ń pè fún àlékún ìjínigbé àtàwọ n ìwà ọ̀daràn míì, tí kò sì ní jẹ́ káwọn aráàlú ní ìgboyà nínú wọn mọ́.

Àwọn aṣòfin náà tẹmpẹlẹmọ pé iṣẹ́ àkọ́kọ́ ìjọba ni láti dá ààbò bo ẹ̀mí àti dúkìá àwọn èèyàn.

Wọ́n ní àwọn ọmọ Nàìjíríà nílò orílẹ̀ èdè tí àwọn ọ̀daràn yóò máa bẹ̀rù àwọn aláṣẹ, kìí ṣe èyí tí àwọn aláṣẹ yóò ti máa bẹ̀rù ọ̀daràn.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here