Ìdí tí mi ò fi se ìgbéyàwó – Allwell Ademola

Ìdí tí mi ò fi se ìgbéyàwó – Allwell Ademola

 

Mary Fágbohùn

 

Osere tiata Allwell Ademola ti safihan idi ti ko fi tii se igbeyawo ninu iforo-wani-lenu-wo to se pelu akegbe re, Biola Bayo.

 

O se iranti bi isele aburu kan se ge emi ololufe re to ye ko se igbeyawo pelu kuru ni bii ogun odun seyin.

 

Ninu fonran kukuru to jade lati ara iforo-wani-lenu-wo ti won ko fi lede naa, Allwell wi pe o ye ki oun se igbeyawo ni odun 2005.

 

Sugbon ti isele laabi kan ja emi afesona re gba titi laye ni bi won se yinbon fun un nigba ti won n soro lori ero ibanisoro.

 

Eni to gbajumo fun ipa ti o ko ninu fiimu ‘You or I’ (2013) ati ‘Omo Emi’ (2017), onirawo fiimu eni odun mokanlelogoji naa so pe isele ibanuje naa ni ipa pupo lori irori ati ilera nipa ti opolo oun.

 

Gege bi o se so, pipadanu ololufe oun ni ona bee da ogbe okan si okan oun fun odun meji.

 

“O ye ki n se igbeyawo ni odun 2005, sugbon o ku ni ojo karun-un osu kokanla, odun kan naa”, ni o so.

 

“Mo n ba soro lori ero ibanisoro ni nigba ti won yinbon fun un. O je iriri ibanuje pupo fun mi. Mo so okan ati ero mi nu fun odun meji. Mi o mo bi ero ibanisoro mi se jabo, mo kan wa nibe”, o fikun un.

 

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here