Ìdí tí ìjọba tún ṣe fi kún owó pásípọ̀ọ́tì sí ₦100,000 àti ₦200,000
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ìjọba àpapọ̀ ti ṣe àfikún iye owó ìwé irinna Nàìjíríà lẹyin bíi ọdún kan ti wọ́n kọ́kọ́ fi owó lé ìwé ìrìnà ọ̀hún.
Ọjọbọ, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 2025 yii ni ajọ to n ri si wọle-wọde ni Naijiria, NIS, kede afinkun naa.
Awọn iwe irinna ti afikun yii kan ni iwe irinna ọlọdun marun un to ni oju awẹ mejilelọgbọn ati iwe irinna ọlọdun mẹwaa to ni oju awẹ mẹrinlelọgọta.
Afikun tuntun wọnyii lo n waye lẹyin ti Olubunmi Tunji-Ojo de ipo minisitita fun ọrọ abẹle.
Ti ẹ ko ba gbagbe, inu oṣu Kẹsan an, ọdun 2024 ni ijọba kọkọ ṣe afikun iye owo iwe irinna naa ti wọn si gbe owo eyii to jẹ ọdun marun lati N35,000 si 50,000, ti wọn tun gbe iye owo eyii to jẹ 70,000 si 100,000.
Ni bayii ijọba tun ti fi kun owo naa, to n tumọ si pe iwe irinna ọlọdun marun to jẹ N50,000 tẹlẹ yoo di N100,000 nigba ti iwe irinna ọlọdun mẹwaa to jẹ N100,000 bayii yoo di N200,000.
Amọ ṣa, afikun yii ko kan awọn to wa nilẹ okeere, awọn to wa ni Naijiria nikan lo kan.
Ki ni idi ti ijọba fi ṣafikun iye owo iwe irinna yii?
Agbẹnusọ ajọ NIS, ACI AS Akinlabi sọ pe afikun owo yii yoo bẹrẹ lati ọjọ Aje, ọjọ kinni, oṣu Kẹsan an, ọdun 2025 yii.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, wọn ṣe afikun naa lati le tunbọ jẹ iki we irinna ọhun jẹ ojulowo ati eyii to ba igba mu.
O ni “Lọna lati ri daju pe iwe irinna Naijiria jẹ ojulowo o si ba igba mu, ajọ wọle-wọde Naijiria kede fikun owo iwe irinna.”
Ajọ NIS tun sọ pe afojusun awọn ni lati ri pe awọn sin araalu ni ọna to tọ ati ọna to yẹ, ati pe awọn araalu ri iwe irinna naa gba lasiko.
Ninu ifọrọwerọ kan pẹlu akọroyin, minisita fun ọrọ abẹle, Tunji Olubunmi-Ojo sọ pe afojusun oun ni lati ri pe awọn eeyan le maa forukọsilẹ lati gba iwe irinna naa lori ayelujara funra wọn.
O ni ohun kan ṣoṣo ti yoo maa gbe awọn eeyan lọ si ọọfisi ajọ naa ko ni lati ya aworan ara rẹ ati lati fi ika rẹ silẹ, awọn ohun to ku ni araalu yoo le ṣe funra wọn lori ayelujara.
Awọn to fẹ forukọsilẹ fun iwe irinna tuntun atawọn to ba fẹ ṣe atunṣe si orukọ wọn yoo le ṣe lori ayelujara lai kọkọ yọju si ọọfisi ajọ NIS.
Ṣaaju asiko yii, o maa n to ọpọ ọsẹ tabi oṣu ki eeyan to le ri iwe irinna rẹ gbọ amọ nnkan ko ri bẹẹ mọ bayii.
Wayi o, NIS ti ni aarin ọsẹ kan pere lawọn eeyan yoo ma ri iwe irinna wọn gba bayii lẹyin afikun owo yii.
Ẹwẹ, ọpọ ọmọ Naijiria lo ti koro oju si afikun owo iwe irinna yii, paapaa lasiko ti nnkan le koko niluu.
Ni kete ti iroyin afikun naa jade lawọn ọmọ Naijiria bẹrẹ si n sọ pe ijọba aninilara ni ijọba to wa lode latari pe kii ṣe irufẹ akoko yii lo yẹ ki ijọba maa fi kun owo iwe irinna.
Koda, awọn kan tilẹ sọ pe ijọba Aarẹ Bola Tinubu n mu aye nira faraalu, bẹẹ lo tun n m u ko nira fun araalu lati fi ilu silẹ.
Lara awọn alẹnulọrọ ilu to bu ẹnu atẹ lu afikun yii ni Peter Obi, oludije sipo Aarẹ to sọ pe niṣẹ ni ijọba to wa lode n mọọmọ di ẹru wuwo le araalu lori.
O ni ko yẹ ki iye owo iwe irinna le to 100,000 naira ambelete 200,000 naira ni orilẹede ti iye owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ ko to 100,000 naira.
Yatọ si Obi, ọpọ awọn ọmọ Naijiria mii lo ni ko yẹ ko ri bẹẹ, paapaa lasiko yii ti ọrọ aje ko ṣe deede ni Naijiria.
Bi o ṣe le gba iwe irinna Naijiria