Ìdí rèé tí Ọlọ́pàá àti Amotekun ṣe kọjú ìjà síra wọn l’Ondo, tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì farapa
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ilé iṣé ọlọ́pàá àtàwọn ẹ̀sọ́ Àmọ̀tẹ́kùn kọlu ara wọn nílùú Akure ní ìpínlẹ̀ Òǹdó lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ́ kẹrin oṣù Kaàrún.
Ohun ti a gbọ ni pe, ede-ai-yede bẹ silẹ laarin awọn agbofinro atawọn ẹsọ Amotekun lori bi wọn ṣe fọwọ ṣinkun ofin mu afurasi kan, Tosin Adebisi, wi pe o ji alupupu ti ọpọ mọ si ọkada gbe.
Adebisic, ẹni ọdun mejidinlogun ni a gbọ pe awọn ẹṣọ Amotekun mu lẹyin ti Alufaa Bola Ariyo ti ijọ Onitẹbọmi Living Word Missionary Baptist Church mu ẹjọ wa pe Adebisi atawọn akẹgbẹ rẹ ti n huwa ọdaran lagbegbe Power Line Ijoka.
Gẹgẹ bi ẹṣọ Amotekun kan ṣe ṣalaye, lẹyin ti Amotekun gba ọkada ti wọn jigbe naa tan, ti wọn si ju afurasi naa si ahamọ, lawọn ọlọpaa de ti wọn si sọ pe ki Amotekun jọwọ afurasi ọhun fawọn.
Bayii lawọn Amotekun ni rara wi pe awọn gbọdọ gbe afurasi naa de olu ileeṣẹ awọn na.
Eyi ni a gbọ pe o jẹ kawọn ẹṣọ Amotekun atawọn ọlọpaa woju ara wọn.
Awọn o ṣoju mi koro ṣalaye wi pe awọn ọlọpaa mii tun wa darapọ mawọn to wa pẹlu awọn ẹṣọ Amotekun, wọn si gbiyanju lati fipa gba afurasi naa.
Bayii ni a gbọ pe awọn ọlọpaa bẹrẹ si ni yin taju taju, koda, a tun gbọ pe wọn tun yinbọn, bo tilẹ jẹ pe awọn ẹṣọ Amotekun ni ọta ibọn naa ko wọle sawọn lara.
Awọn ẹṣọ Amotekun ni ọpọ tajutaju lawọn ọlọpaa yin, bakan naa si ni wọn tun yinbọn AK-47.
Olori awọn ẹṣọ Amotekun to jẹ obinrin, to mu afurasi naa ni a gbọ pe o farapa ni ori rẹ.
Awọn ẹṣọ Amotekun mẹsan an ni a gbọ pe wọn wa nile iwosan bayii nibi ti wọn ti n gba itọju lẹyin ti wọn farapa nibi iṣẹlẹ naa.
Bakan naa ni a gbọ pe awọn irinṣẹ awọn ẹṣọ Amotekun bii foonu, redio ibaraẹnisọrọ atawọn nnkan mii lawọn ọlọpaa gba, ti wọn si bajẹ.
Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti ṣalaye pe awọn ọlọpaa n ṣiṣẹ wọn laarọ ọjọ Aiku to kọja ni lati mu afurasi to ji alupupu gbe nile ijọsin kan ati lati gba a pada.
Agbẹnusọ ọlopaa Ondo, DSP Ayanlade Olayinka Olushola, ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita lori iṣẹlẹ ọhun wi pe awọn ọlọpaa lo kọkọ de ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye kawọn Amotekun to de bii ologun lori ọkada.
DSP ni ọlọpaa kan farapa ninu ikọlu ọhun.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ọga agba Amotekun ati ileeṣẹ ọlọpaa pada dasi ọrọ naa eyi to jẹ ki awọn Amotekun jọwọ afurasi naa fawọn ọlọpaa atawọn nnkan ti wọn gba lọwọ rẹ.
Ibẹru-bojo gbalẹ nigba tawọn ẹṣọ Amotekun ti inu wọn ko dun pẹlu bi awọn ọlọpaa ṣe gba afurasi naa bẹrẹ si ni yinbọn soke.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ni lati yin tajutaju lati le dẹkun rogbodiyan ọhun.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni irọ nla ni iroyin to sọ pe awọn ẹsọ Amotekun atawọn ọlọpaa kọju ibọn si ara awọn.
Ileeṣẹ ọlọpaa Ondo ni awọn ko ni kaarẹ lati ri pe awọn ọlọpaa n ṣiṣẹ wọn lọna to ba ofin mu, nigba ti wọn rọ awọn ẹṣọ eleto abo yoku lati maa tẹle alakalẹ lori eto abo fun araalu.