Oludije fun ipo aare labe asia egbe oselu Labour Party (LP), Ogbeni Peter Obi, ti so pe ilepa ipo aare re wa fun ojo iwaju orile ede yii lai fi ti esin tabi eya se.
Obi so eyi ni Enugu ni ibi apejo “Seto ojo iwaju” ti ajo kan to n je Boys Champion (BC) se agbekale re.
Obi gba awon odomokunrin naa niyanju lati mase dibo fun eya tabi esin, o tenumo pe ko si esin kan tabi eya kan ti yoo ra bugan tabi iresi ni edinwo bi orile ede ti se wa bayii.
“Mo je eni ti o n wa ise, idi niyi ti mo fi wa niwaju eyin olugbasise mi (odo, youths) ati wi pe akoko awon odo Naijeria niyi lati gba orile ede won.
“Mo je olufarasin fun ise naa, ki e si fa mi laso bi mo ba ja yin kule. Ti e ba se ohun ti ko dara leni, ojo iwaju yoo gbesan lara yin,” o se ikilo fun won.
Obi ro awon odo lati dibo fun eni ti o kun oju osuwon nikan ati adari ti o se e gbagbo ti yoo le e yi ojo iwaju won pada leyin idibo odun 2023 to n bo.
“Mejidinlogun ninu wa ni yoo so ohun kan sugbon e gbodo ri aridaju ohun ti won n so fun yin. Ko si aaye fun agbeyewo ni 2023.
“A o yo agbekale oran dida won, a o si dipo re pelu agbekale idagbasoke,” ni ohun ti Obi so.
Gomina ipinle Anambra tele ri naa so pe oun yoo se ipese aabo to daju fun gbogbo omo Naijeria ki aaye le gba awon agbe lati le pada si oko won ki owon gogo ounje le e dinku.
“A o pese awon osise aabo nipa gbigba awon eniyan si ise olopa ati fifun won ni ohun elo lati le gbogun ti aisi aabo.
“Ona kan soso re ti a fi le gbe Naijeria lati ipo jegudujera si ipo awujo ti o leso ni nipa ninawo sori awon odo ati wi pe Naijeria gbodo bo ara re.
“Ijoba mi yoo yo owo iranwo lori epo, yoo si lo owo naa lati da ise sile fun awon odo, eyi ni ojo iwaju ti a fe mu wa,” Obi se afikun.